Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Ẹṣọ alaabo ti wọn n jẹ Amọtẹkun ti bẹrẹ iṣẹ lati ṣawari Abilẹkọ kan, Oluwatoyin Gbemisọla Ojo, ti awọn agbebọn ji gbe niluu Oṣogbo lalẹ ọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ to kọja.
ALAROYE gbọ pe ninu ile obinrin ẹni ọdun mọkanlelaaadọta ọhun, to wa ni Landẹro Street, agbegbe Technical College, niluu Oṣogbo, ni awọn agbebọn naa ti ji i gbe ni nnkan bii aago mẹwaa aabọ alẹ.
Alakooso awọn Amọtẹkun nipinlẹ Ọṣun, Amitolu Shittu, ṣalaye pe ni nnkan bii aago kan oru kọja iṣẹju diẹ lọjọ Abamẹta, Satide, ni ọkọ obinrin naa, Ọgbẹni Oluwasanmi Ojo, to jẹ oṣiṣẹ pẹlu ile ifọpo NNPC, Warri, fi iṣẹlẹ naa to awọn leti.
Amitolu sọ siwaju pe kia loun atawọn eeyan oun ti fọn sinu igbo lagbegbe naa lati ṣawari obinrin naa.
O fi da awọn araalu loju pe obinrin naa yoo jẹ riri, ati pe ọwọ yoo tẹ awọn ti wọn ṣiṣẹ laabi ọhun.