Adefunkẹ Adebiyi,Abẹokuta
Ẹṣọ alaabo ilẹ Yoruba, Amọtẹkun, yoo bẹrẹ iṣe pẹrẹwu nipinlẹ Ogun ninu oṣu kin-in-ni ọdun 2021 ta a ṣẹṣẹ mu yii, gẹgẹ bi Gomina Ọmọọba Dapọ Abiọdun ṣe sọ.
Ninu ọrọ ikini ọdun ti Gomina Abiọdun ba awọn eeyan ipinlẹ Ogun sọ laaarọ ọjọ kin-in-ni, oṣu kin-in-ni, ọdun 2021 lo ti sọ ọ di mimọ pe yatọ si Amọtẹkun ti yoo bẹrẹ iṣẹ, ijọba oun yoo tun bẹrẹ eto lori fifun awọn olugbe ipinlẹ Ogun ni kaadi idanimọ, eyi ti wọn yoo fi ṣe akọsilẹ iye eeyan to n gbe nipinlẹ yii.
Nigba to n sọrọ lori idi to fi ṣe pataki lati jẹ ki Amọtẹkun tete bẹrẹ iṣẹ, gomina ṣalaye pe ikunlọwọ gidi ni ikọ naa yoo jẹ fawọn ọlọpaa atawọn agbofinro to ku, ati pe erongba oun lati mojuto aabo araalu, igbaye-gbadun wọn, eto ẹkọ, ọgbin, riro awọn ọdọ lagbara, ipese ileegbe ati bẹẹ bẹẹ lọ ko yingin, gbogbo rẹ ni ijọba oun yoo ri i pe o wa si imuṣẹ.
Kọmanda tuntun ni wọn yan fun idari Amọtẹkun nipinlẹ yii bi gomina ṣe wi, ọga ọlọpaa to ti ṣiṣẹ nipo giga kaakiri Naijiria ni ọkunrin naa, iyẹn David Ajibọla Akinrẹmi.
Bi ko ba jẹ ti Korona to wọle lọdun 2019 ni, ọpọ iṣe idagbasoke ni ko ba waye gẹgẹ bi gomina ṣe wi, o ni ṣugbọn pẹlu ẹ naa, iṣakoso oun ko ṣai gba awọn ami ẹyẹ bii gomina to kunju oṣuwọn ju lẹka aabo, lẹka ẹkọ, ọgbin ati ipese ileegbe fawọn eeyan kaakiri agbegbe.
Gomina dupẹ lọwọ awọn eeyan ipinlẹ Ogun fun ifẹ ati aduroti wọn lori iṣakoso ẹ, o rọ wọn lati maa tẹle ofin Korona nigba gbogbo. Bẹẹ loni kawọn ọba, awọn baalẹ ati aṣaaju agbegbe kaakiri maa la awọn eeyan wọn lọye pe Korona ẹlẹẹkeji ti wa nita, ki kaluku ṣọra ṣe.