Awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun kọju ija sira wọn l’Akungba-Akoko, eeyan meji lo ti ku

Aderounmu Kazeem

O kere tan, eeyan meji ni wọn ti padanu ẹmi wọn bayii lori ija to n lọ laarin awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun nipinlẹ Ondo.

ALAROYE gbọ pe nitori iku ojiji ti wọn fi pa ọkunrin kan to n jẹ Babatunde Adeluka Olubasa sinu otẹẹli ẹ lo jẹ ki ọrọ ọhun tubọ fẹju si i.

Nile ounjẹ kan ti Babatunde kọ siluu Akungba-Akoko lẹgbẹẹ Yunifasiti ni wọn ti lọọ ka a mọ, ti awọn ọkunrin mẹta kan si pa a sibẹ.

Ọkan lara awọn olugbe agbegbe naa sọ pe nitori iku ojiji ti wọn fi pa ọkunrin yii lo bi awọn eeyan kan ninu ti wọn fi pa eeyan meji bayii, lati fi gbẹsan bi wọn ti ṣe pa Babatunde.

Lara awọn to ba iṣẹlẹ ọhun lọ ni ọkunrin kan ti wọn n pe ni “AY Killer”, eyi to tumọ si AY apaayan.

Agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọlọpaa l’Ondo, Ọgbẹni Tee-Leo Ikoro, ti sọ pe kọmiṣanna ọlọpaa, Bọlaji Salami, ti pa awọn laṣẹ lati tu iṣu de isalẹ ikoko iṣẹlẹ naa.

Awọn ẹṣọ agbofinro ti wọn n gbogun tawọn ọmọ elẹgbẹ okunkun ti wa lagbegbe naa bayii lati fopin si wahala ọhun.

 

Leave a Reply