Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
Lẹyin ti ajọ eleto idibo ti kede gbogbo oludije lorukọ ẹgbẹ oṣelu APC funpo Sẹnetọ ati aṣoju-ṣofin gẹgẹ bii ẹni to jawe olubori ninu eto idibo to waye ni Satide, ọjọ Abamẹta, ọsẹ to kọja yii, minisita tẹlẹ fun ere idaraya nilẹ yii, Bọlaji Abdullahi, to dije funpo sẹnetọ, to si fidi-rẹmi sọwọ Saliu Mustapha, ni Aarin-Gbungun ipinlẹ Kwara atawọn oludije sipo aṣoju-sofin mi-in ti ni awọn ko gba abajade esi idibo naa wọle.
Nigba to n sọrọ, o ni ojooro ni wọn ṣe, to si ta ko ilana ati ofin eto idibo nilẹ yii, fun idi eyi, oun ko gba esi idibo naa wọle. O waa fi awọn alatilẹyin rẹ lọkan balẹ pe oun yoo gba ẹtọ oun pada nile-ẹjọ.
Aarọ kutu ọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii, ni ajọ eleto idibo ipinlẹ Kwara kede Saliu Mustapha gẹgẹ bii ẹni to jawe olubori lasiko eto idibo naa. Ibo ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un kan le mẹsan-an ati ọgọrin le mẹtalelogun (109,823), ni oludije ẹgbẹ oṣelu APC yii ni. Nigba ti Bọlaji Abdullahi to jẹ ọmọ ẹgbẹ PDP ni ibo ẹgbẹrun lọna mọkadinlaaadọje ati igba din meje (69, 193).
Bakan naa ni Rafiu Ibrahim, oludije funpo sẹnetọ ni Guusu Kwara naa ni oun ko gba esi ibo yii wọle, o ni idibo naa kun fun oniruuru mago-mago lẹkun idibo Guusu Kwara. O tẹsiwaju pe awọn lọọya oun ti wo esi ibo naa daadaa, wọn yoo si gbe igbesẹ ofin laipẹ.
Awọn to tun kọ esi idibo ti wọn kede ni Abdulwahab Isa, oludije funpo aṣoju-ṣofin ilẹkun idibo Ila-Oorun ati Guusu Ilọrin (East/Ilọrin South), Dare Bankọle ati Ibrahim Ajia, Ekiti/Oke-Ẹrọ/Isin/Ọyun ati Iwọ-Oorun Ilọrin ati Asa (West/Asa), tawọn naa dije funpo aṣoju-ṣofin lẹkun idibo wọn.