APC Ọṣun ni arumọje ni aṣeyọri ọgọrun-un ọjọ Gomina Adeleke, lawọn PDP ba ni iwọfa lẹnu

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress (APC) ati Peoples’ Democratic Party (PDP) nipinlẹ Ọṣun ti n takoto ọrọ siraa wọn lori awọn aṣeyọri tijọba Gomina Ademọla Adeleke ṣe lori aleefa laarin ọgọrun-un ọjọ to ti di gomina.

Bi ẹgbẹ APC ṣe gba pe sakamanje, itanjẹ lasan, ni awọn aṣeyọri ti Adeleke ka silẹ fun awọn oniroyin pe ijọba oun ti ṣe, bẹẹ ni ẹgbẹ PDP sọ pe ijakulẹ ti APC ba pade lasiko idibo gomina to kọja ọhun lo ṣi n ṣe wọn bii ala.

Alaga ẹgbẹ APC, Sooko Tajudeen Lawal, lo ba awọn oniroyin sọrọ niluu Oṣogbo, nibẹ lo ti sọ pe laarin oṣu mẹta pere, owo to jẹ biliọnu lọna aadọrun-un Naira lo wọle si asunwọn ijọba ipinlẹ Ọṣun labẹ Adeleke, ki waa lo fi owo naa ṣe?

Lawal ṣalaye pe, yatọ si biliọnu mẹẹẹdogun Naira tipinlẹ Ọṣun gba latọdọ ijọba apapọ, iyẹn FAAC, biliọnu mọkanla Naira tun wọle lati Siftas, biliọnu marun-un Naira lati NG Cares, bẹẹ ni wọn gba biliọnu to din diẹ ni meje Naira asẹsilẹ owo-ori latọdọ ijọba apapọ.

O fi kun ọrọ rẹ pe yatọ si biliọnu mẹrinla Naira ti Oyetọla fi silẹ sinu asunwọn ijọba ko too lọ, Adeleke ba biliọnu to le diẹ ni mẹta Naira gẹgẹ bii owo akanṣe iṣẹ fawọn obinrin, bẹẹ lo ti gba nnkan bii biliọnu marun-un Naira owo to wa fun agbegbe.

Lawal ṣapejuwe ọgọrun-un ọjọ Gomina Adeleke lori aleefa gẹgẹ bii eyi to kun fun ina-apa, iwa-ika ati eyi to da bii ejo to kọja lori apata lai ni ipa nitori juuju nijọba naa fi n bo awọn araalu loju, ṣe lo si n fi ẹyin pamọ, to n fun wọn lokuta.

O ni laarin ọgọrun-un ọjọ yii ni Adeleke ti da awọn olukọ ẹgbẹrun kan aabọ tijọba Oyetọla gba duro, o da awọn dokita ẹẹdẹgbẹta duro, o da awọn olounjẹ ti wọn n fun awọn ọmọleewe lounjẹ ọfẹ silẹ, o da awọn ọdọ OYES silẹ, o si pa ala awọn Ijeṣa lati ni Fasiti run.

O sọ siwaju pe ijọba Oyetọla ti fun kọngila to n ṣe oju ọna Oṣogbo-Ikirun-Kwara Boundary ni biliọnu kan Naira, iyalẹnu lo si jẹ pe Adeleke tun sọ pe ara awọn ọna ti oun fi owo ijọba ipinlẹ Ọṣun ṣe ni.

Amọ ṣa, Adele alaga ẹgbẹ oṣelu PDP nipinlẹ Ọṣun, Dokita Adekunle Akindele, sọ pe alailoye ni ẹgbẹ APC, o si ṣe ni laaanu pe aṣọ ko ba ọmọyẹ wọn mọ.

O ni gbogbo awọn araalu ni wọn ti mọ pe Gomina Adeleke ki i ṣe gbewiri bii awọn kan, nitori gbogbo afojusun rẹ ni lati mu idagbasole ti ko lẹgbẹ ba ipinlẹ Ọṣun kiakia.

Adekunle ni ẹgbẹ naa ko ni imọ kankan nipa pe aye ti yi kuro nibi ti atijọ, aye ti lu jara bayii, bẹẹ ni wọn ko ri sisan gbese owo ajẹmọnu awọn oṣiṣẹ atawọn oṣiṣẹ-fẹyinti gẹgẹ bii aṣeyọri to mu ara tu awọn araalu.

O ni aturọta bii elubọ ni wọn, idi si niyẹn ti awọn araalu fi gbọdọ tubọ le wọn wọle patapata nipinlẹ Ọṣun nipasẹ idibo ileegbimọ aṣofin to n bọ lọna.

Leave a Reply