Jide Alabi
Lẹyin ọjọ mẹrinla to ti wa nibi ti wọn ti n tọju ẹ, nitori arun Koronafairọọsi to kọ lu u, ara Gomina Babajide Sanwo-Olu ti ya daadaa bayii, bẹẹ lo ti ba awọn oniroyin sọrọ paapaa.
Lọsan an, Ọjọbọ, Tọsidee yii, ni wọn yọnda gomina nibi ti wọn ti n tọju ẹ, lẹyin aridaju pe arun Koronafairọọsi ọhun ti kuro lara ẹ patapata.
Ninu ọrọ ti Akọwe gomina fun eto iroyin, Ọgbẹni Gboyega Akọsile, fi sori ikanni abẹyẹfo ẹ lo ti fidi ọrọ ọhun mulẹ.
Ọjọ kejila, oṣu yii, ni Kọmiṣanna fun eto ilera, Akin Abayọmi, kede pe gomina ipinlẹ Eko ti ko arun Korona. Latigba naa ni wọn si ti fi Ọgbẹni Babajide Sanwo-Olu si ipamọ, nibi ti wọn ti n tọju ẹ, ki ara ẹ too ya bayii.