Bi a ti n royin yii, iyawo Aarẹ Muhammadu Buhari, Aisha, ti wa ni Dubai, ileeewosan nla kan nibẹ ni wọn gbe e lọ, ara rẹ ko ya gidigidi. Lojiji ni wọn sare gbe e lọ sọhun-un lasiko isinmi ọdun Ileya, nigba ti kinni to n ṣe e naa le si i. Ọrun ni wọn sọ pe o n dun un, aisan ọrun naa si wọ ọ lara kọja bo ṣe yẹ.
Ki i ṣe akọkọ niyi ti ọrun yoo dun obinrin naa bi Alaroye ti gbọ. Ni ọdun 2019 to kọja yii, ohun to jẹ ki Aisha lọ siluu oyinbo ree, to si pẹ nibẹ titi, ni gẹrẹ ti wọn dibo ọdun naa tan. Itọju yii lo n gba ti ko tete wale ti ariwo fi gbagboro pe awọn kan fẹẹ fẹyawo fun ọkọ rẹ nigba naa. Nigba to pada de, oun paapaa sọ pe ara oun ko ya ni, loootọ si loun lọọ gba itọju lẹyin-odi.
Asiko to wa si Eko, to si tun lọ si Ibadan nile awọn Arabinrin Ajimọbi lati ki i fun ti ọkọ rẹ to ku, ni wọn ni aisan naa tun bẹrẹ ni gbara to pada si Abuja. Awọn eeyan ro pe aiyaara naa yoo tete lọ ni, afi bo ṣe n le si i. Igba ti awọn eeyan ko wa ri i rara fun ti ọdun Ileya yii ni wọn mọ pe kinnni naa ti kuro ni kekere. Awọn kan tilẹ sọ pe o ṣee ṣe ko jẹ nitori aisan Aisha gan-an ni Buhari funra ẹ ṣe ni ki ẹnikẹni ma wa sile oun lasiko ọdun yii, pe ki kaluku ṣe ọdun nile wọn.
Ni gbogbo asiko naa ni wọn n ṣeto, ti wọn si gbe Aisha lọ si Dubai, pe bi apa ko ba si ka a nibẹ, wọn yoo gbe e lọ sibomi-in, nibi ti yoo ti ri itọju to peye. Ṣugbọn ni bayii, ara iyawo Aarẹ wa ko ya, o wa niluu oyinbo, ka gbadura fun un ki Ọlọrun tete ba wa mu un lara da.
Ki Olorun bawa mu ara Aya aare wa ya
Sebi kosi osipita ni iluyi mo . Tiwonlegbe iyawo are lo . AFI ilu oyinbo .hmm . Itiju nla gbaa loje fun ijoba Nigeria.