Ara kenge: APC ṣedanwo fawọn ondije sipo alaga kansu wọn ni Kaduna

Faith Adebọla

Afi bii ẹni fẹẹ ṣedanwo Wayẹẹki tabi Jambu, lawọn ti wọn wọn fẹẹ dije sipo alaga ijọba ibilẹ ninu eto idibo to bọ nipinlẹ Kaduna jooko sori aga pẹlu agbada wọn, ti wọn mu gege ati iwe ajakọ, wọn bẹrẹ si i dahun awọn ibeere ninu idanwo ti ẹgbẹ APC ṣe fun wọn l’Ọjọruu, Wẹsidee yii.

Otẹẹli Stone-Hedge, to wa niluu Kaduna, ni idanwo ati ifọrọwanilẹnuwo naa ti waye. Igba akọkọ ree tiru nnkan bẹẹ maa ṣẹlẹ, ara tuntun si lọrọ ọhun jọ loju ọpọ eeyan to gbọ nipa rẹ.

Yatọ si ti idanwo alakọsilẹ, awọn ondije naa tun ni lati jokoo siwaju igbimọ oluṣayẹwo ẹlẹni mẹtadinlogun kan, ti wọn ṣe intafiu (interview) fun wọn bii igba teeyan n waṣẹ nileeṣẹ kan. Lara awọn to wa lara igbimọ ọhun ni awọn ọjọgbọn ni fasiti, awọn amofin atawọn ọmọwe tẹgbẹ APC ti yan ṣaaju.

Gẹgẹ ba a ṣe gbọ, lara ibeere ti wọn ni kawọn ondije fun ipo alaga ọhun kọ ni itan igbesi-aye wọn, awọn ileewe ti wọn lọ, iṣẹ ti wọn ṣe ati iriri ti wọn ti ni, awọn ilu wo ni wọn ti de ri tabi ti wọn ti gbe ri nipinlẹ Kaduna, ni Naijiria ati loke okun. Wọn tun beere pe ki wọn kọ arokọ kan lede oyinbo nipa imọ wọn lori iṣẹ ijọba, iṣẹ ilu ati iṣakoso rere.

Ajọ eleto idibo ipinlẹ Kaduna (Kaduna State Electoral Commission) ni wọn lo dari idanwo alakọsilẹ tawọn ondije naa ṣe, wọn lawọn ti wọn ba feeli idanwo yii ko ni i le kopa ninu eto idibo sipo alaga ijọba ibilẹ to n bọ ọhun.
Ajagun-fẹyinti loju ofurufu, Emmanuel Jekada, to jẹ alaga fun ẹgbẹ All Peoples Congress nipinlẹ Kaduna sọ pe lajori idi tawọn fi ṣeto idanwo naa ni lati tubọ mọ bawọn to fẹẹ dije ṣe kunju oṣuwọn si, ati boya loootọ ni wọn jẹ ẹni ti wọn sọ pe awọn jẹ ninu awọn iwe ti wọn ti fi ṣọwọ ṣaaju.

O ni gbogbo ọna ni ẹgbẹ APC n ṣan lati mu adinku ba awuyewuye ẹjọ lẹyin idibo. O lawọn fẹẹ ko ṣe kedere si gbogbo eeyan pe ki i ṣe ojuṣaaju lawọn fi ja ẹnikẹni ti ko ba kunju oṣuwọn bọ.

Sibẹ, ọpọ eeyan lori atẹ ayelujara lo ti sọrọ lodi si igbesẹ ọhun, wọn ni aṣeju lẹgbẹ oṣelu APC n ṣe.

Leave a Reply