Adewale Adeoye
Ọdọ awọn ọlọpaa agbegbe Rio de Janeiro, lorileede Brazil, ni iyaale ile kan, Abilekọ Erika De Souza Nunes, wa bayii. Ẹsun tawọn agbofinro ilu ọhun fi kan an ni pe o gbe oku ẹgbọn baba rẹ, Oloogbe Paulo Roberto Braga, ẹni ọdun mejidinlaaadọrin, wa si banki agbegbe naa lati waa fi wa ya owo.
ALAROYE gbọ pe iṣẹlẹ ọhun waye lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹrindinlogun, oṣu Kẹrin, ọdun 2024 yii.
Ẹgbẹrun mẹta o le irinwo dọla owo ilẹ okeere ni Erika fẹẹ ya ni banki ọhun, ṣugbọn ẹgbọn baba rẹ to maa ṣoniduuro fun un ku ni nnkan bii wakati mẹta si akoko ti wọn maa fun un ni owo ele naa.
Bi Erika ṣe n gbiyanju lati tọwọ oloogbe naa bọwe ni banki, bẹẹ ni oloogbe naa n sori kodo, ti ko si le ṣohun Kankan.
Ṣe ni Erika n pariwo le oku oloogbe naa lori pe o gbọdọ tọwọ bọwe k’oun baa le ri owo ele naa gba lọjọ naa.
Nigba tawọn alaṣẹ banki ọhun ṣakiyesi pe oku ni Erika gbe wa si banki ni wọn ba tete ranṣẹ pe awọn ọlọpaa pe ki wọn waa fọwọ ofin mu un kuro lọdọ awọn.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Rio-De Janeiro, lorileede Brazil, Ọgbẹni Fabio Luiz, to fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ fawọn oniroyin l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kẹtadinlogun, oṣu Kẹrin, ọdun yii, sọ pe iyalẹnu nla gbaa lọrọ Erika jẹ fawọn pe o gbe oku ẹgbọn baba rẹ waa fi yawo ni banki.
O ni oriṣii ẹsun iwa ọdaran mẹta lawọn maa fi kan an lasiko tawọn ba foju rẹ bale-ẹjọ laipẹ yii.
Ẹsun akọkọ ni pe, o gbe oku ẹgbọn baba rẹ waa yawo, ẹsun keji ni pe o fẹẹ dọgbọn yawo lọna eru, ati pe o n ṣe oku ẹgbọn baba rẹ baṣubaṣu nita gbangba lọna ti ko bofin mu.