Ondo ni wọn ti mu baale ile kan to pa iyawo rẹ ni Adamawa

Adewale Adeoye

Ipinlẹ Ondo lawọn alaṣẹ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Adamawa ti pada mu baale ile kan, Ọgbẹni Riba Kwanta, ẹni ogoji ọdun to n gbe lagbegbe Bode, nijọba ibilẹ Shellenga, nipinlẹ Adamawa, tẹlẹ.

Ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu Kejila, ọdun 2023 to kọja yii, ni Riba gbẹmi iyawo ile rẹ,  Oloogbe Godiya Akwale, sinu ile ti wọn n gbe to wa lagbegbe Bode, ṣugbọn to tilẹkun mọ ọn sibẹ, lo ba sa lọ rau.

Latigba naa si lawọn ọlọpaa agbegbe ọhun ti n wa a ko too di pe ọwọ ṣẹṣẹ tẹ ẹ l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kẹtadinlogun, oṣu Kẹrin, ọdun 2024 yii.

ALAROYE gbọ pe ọrọ ti ko to nnkan lo dija silẹ laarin awọn mejeeji, kawọn araale ibi ti wọn n gbe too mọ ohun to n ṣẹlẹ, Riba ti gbẹmi iyawo rẹ sinu ile lọjọ naa.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa S.P Suleiman Nguroje to fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ fawọn oniroyin l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kẹtadinlogun, oṣu Kẹrin, ọdun yii, sọ pe gbara ti Riba hu iwa to lodi sofin ọhun tan lo ti sa lọ kọwọ ma baa tẹ ẹ ṣugbọn ọwọ pada tẹ ẹ ni agbegbe kan nipinlẹ Ondo, laipẹ yii.

O ni awọn maa too foju Riba bale-ẹjọ laipẹ yii, ko le jiya ẹṣẹ ohun to ṣe lẹkun-un-rẹrẹ.

 

Leave a Reply