Iyalẹnu ni ọrọ obinrin ẹni ọdun marundinlogoji kan ṣi n jẹ fun awọn dọkita ọsibitu kan ti wọn n pe ni Habib Bourguiba University, ni ilu kan ti wọn n pe ni Sfax, lorileee Tunisia, pẹlu bi wọn ṣe ba afọku tọmbila imumi to to iwọn sẹntimita mẹjọ, (8cm) ninu ile-itọ obinrin naa.
Ohun ti awa ri gbọ nipa iṣẹlẹ naa ni pe o ti to ọjọ mẹta ti obinrin yii ti maa n ni inira to ba fẹẹ tọ. Nigba ti inira naa si n pọ si i lojoojumọ ni obinrin yii gba ileewosan lọ pe ki awọn dokita ba oun ri si ohun to n ṣe oun ti oun ko fi le tọ daadaa yii.
Gbogbo ero awọn dokita si ni pe boya o ti ko arun kan ti ki i jẹ keeyan tọ daadaa ni ki i ṣee le e tọ bo ṣe yẹ. Ni wọn ba ṣe ayẹwo si inu rẹ lati le mọ ohun to wa nibẹ gan-an.
Lasiko ayẹwo naa ni wọn sọ pe okuta nla kan to to iwọn sẹntilita mẹjọ lo wa ninu ile itọ rẹ, afi bi wọn ba si ṣe iṣẹ abẹ fun un ki wọn too le yọ okuta naa kuro.
Niwọn igba ti ọrọ naa si ti n ko inira ba obinrin ara Tunisia yii, oju ẹsẹ lo gba ki wọn ṣiṣẹ abẹ fun oun ko le ni igbadun lara rẹ.
Ṣugbọn iyalẹnu lo jẹ fun dokita atawọn ara ọsibitu ti obinrin yii ti lọọ ṣiṣẹ abẹ yii nigba ti wọn la ile-itọ rẹ, to si jẹ pe kaka ki wọn ba okuta ti sikaani (scan) gbe jade, afọku tọmbila nla kan ni wọn ba ninu obinrin naa. Lati bii ọdun mẹrin lo si ti wa nibẹ to ti n gbe e kiri.
Nigba ti gbogbo eeyan n beere tiyanu tiyanu pe bawo ni tọmbila to tobi to bẹẹ yoo ṣe wọnu eeyan, dokita to ṣiṣẹ abẹ naa sọ pe o ṣee ṣe ko jẹ pe nigba ti wọn n ba obinrin naa lo pọ lọna ti ko yẹ ni afọku tọmbila ọhun wọnu rẹ, bo tilẹ jẹ pe ko le fidi eleyii mulẹ.