Ọwọ tẹ awọn ọlọpaaa to yinbọn mọ ọmọ Poli Eruwa

Ọlawale Ajao, Ibadan

Ni nnkan bii aago kan aabọ ọsan ọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ to kọja, niṣẹlẹ ọhun waye, nigba ti awọn kan ninu awọn ọlọpaa to n ṣọ oju ọna Eruwa s’Ibadan deede yinbọn mọ awọn akẹkọọ ileewe Adeṣeun Ogundoyin Polytechnic, Eruwa, meji kan ti wọn n ti ilu Eruwa lọ s’Ibadan jẹẹjẹ wọn.

Gẹgẹ b’ALAROYE ṣe gbọ, ọkan ninu awọn akẹkọọ ọhun, Samuel Akinṣuyi, to ni mọto ọhun naa lo n wa a. Nigba tawọn ọlọpaa naa da wọn duro, wọn kọ lati duro, eyi lo fa a ti ọkan ninu awọn agbofinro naa fi yinbọn si ọkọ ọhun, ti ibọn si ba Samuel.

Ọkan ninu awọn akẹkọọ ọhun, Akindele Ọladimeji,  to ba wa sọrọ sọ pe, “nitori pe ọlọpaa beere owo lọwọ Samuel, ṣugbọn ti ko fun wọn, ni wọn ṣe yinbọn mọ ọn ni kokosẹ.

Wọn ti fi ibọn ba kokosẹ rẹ kan jẹ tan papata. Ẹni to ba ri i bi ọta ibọn ṣe fọ ọ yoo ti mọ pe wọn mọ-ọn-mọ yinbọn yẹn mọ ọn ni.

“Akẹkọọ Business Studies (ẹkọ imọ idari okoowo) ni Samuel. O ṣẹṣẹ pari ND 2 (ipele akọkọ nileewe gbogbonise) ni.”

Ṣaaju lẹgbẹ awọn akẹkọọ ileewe giga lorileede yii, National Association of Nigerian Students (NANS), ti naka aleebu sileeṣẹ ọlọpaa ilẹ yii, to si rọ wọn lati ṣewadii iṣẹlẹ naa.

Wọn ni ibọn ti wọn yin mọ ọmọkunrin naa ti fẹẹ fa aisan rọpa-rọsẹ si i lara bayii nitori ko le fẹsẹ rẹ mejeeji rin daadaa mọ.

Lọjọ Aje ọsẹ yii lọga awọn ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ, CP Ngozi Onadeko, fidiẹ ẹ mulẹ pe awọn ti ṣewadii iṣẹlẹ ọhun tan, awọn si ti mu awọn ọlọpaa to lọwọ ninu iṣẹlẹ naa.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, nipasẹ SP Adewale Ọṣifẹṣọ ti i ṣẹ alukoro rẹ, ‘Loju ẹsẹ ta a ti gbọ nipa iṣẹlẹ yii la ti bẹrẹ iwadii. Ohun ti awọn ọlọpaa yẹn sọ ni pe nitori pe awọn ṣẹwọ si Samuel ati ọrẹ ẹ ti wọn jọ wa ninu mọto lati duro ṣugbọn ti wọn ko dahun lawọn ṣe yinbọn si taya ọkọ yẹn lati le da wọn duro.’

Bo tilẹ jẹ pe ko darukọ awọn agbofinro ọhun, ọga agba awọn ọlọpaa yii sọ pe ọwọ ti tẹ wọn bayii, ati pe titi di ba a ṣe n sọrọ yii, inu atimọle ọlọpaa lawọn mejeeji wa ti wọn n jiya ẹṣẹ wọn.

Leave a Reply