Faith Adebọla, Eko
Ko jọ pe inu awọn eeyan dun si eto ọkọ oju-irin Eko s’Ibadan tijọba ṣe akojade rẹ bii ọmọ tuntun l’ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, pẹlu bo ṣe jẹ pe ẹyọ ero kan ṣoṣo lo wọ reluwee naa lati Eko si Ibadan.
Eyi ko ṣẹyin owo reluwee naa tawọn araalu lo ti wọn ju. Nitori ẹ ni wọn ṣe kegbajare sijọba lati fa owo ọkọ naa walẹ, wọn niye owo ti wọn bu le ọkọ naa ti ga ju agbara wọn lọ.
Minisita fun eto irinna ọkọ, Rotimi Amaechi, lo kede lọsẹ to kọja pe gbogbo eto ti pari lori reluwee tuntun naa, o lo maa bẹrẹ iṣẹ lọsẹ yii, ṣugbọn owo tawọn eeyan yoo maa wọ ọ lati Eko si Ibadan jẹ ẹgbẹrun mẹta naira (#3,000) fun aaye gbogbogboo, ẹgbẹrun marun-un naira (#5,000) fun aaye ọlọla (Business class), tawọn to ba si fẹẹ jokoo laaye akọkọ (First class) yoo san ẹgbẹrun mẹfa (#6,000).
O fi kun un pe yatọ si ti gbogbogboo, ẹrọ amuletutu ati awọn nnkan idẹra loriṣiiriṣii lawọn pese sawọn aaye meji to ku ọhun.
Bawọn araalu ṣe gbọ ikede yii ni wọn ti pariwo pe owo tijọba gbe le reluwee yii ti pọ ju. Niṣe lawọn araalu n sọko ọrọ sijọba, wọn ni ko jọ pe mẹkunnu wa lara awọn ti wọn ṣeto reluwee naa fun.
Maneja ileeṣẹ reluwee lagbegbe Eko, Ọgbẹni Jerry Oche, naa fidi rẹ mulẹ pe ero kan lọkọ naa gbe lati Eko de Ibadan lọjọ Aje, o ni boya nitori o jẹ ọjọ akọkọ ni. Bo tilẹ jẹ pe ọkọ ọhun duro l’Abẹokuta, ṣugbọn ko si ero kankan to wọle, bẹẹ ni ko sẹni to gba tikẹẹti, titi to fi de Ibadan.
Iwadii ti akọroyin wa ṣe fi han pe reluwee naa ko lọ lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, eyi ṣee ṣe ko jẹ nitori ijakulẹ ti wọn ba pade lọjọ akọkọ lo fa a. Ko si ti i daju boya ijọba yoo mu adinku ba owo ọkọ naa.