Awọn tọọgi kọ lu awakọ agbẹjọro Jẹgẹdẹ nibi ijokoo igbimọ to n gbọ ẹsun idibo l’Akurẹ

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Diẹ lo ku ki nnkan mi-in bẹ silẹ nibi ijokoo igbimọ to n gbọ awuyewuye to su yọ ninu eto idibo gomina ipinlẹ Ondo to n lọ lọwọ nile-ẹjọ giga kejì to wa l’Akurẹ laaarọ ọjọ Isẹgun, Tusidee, ọsẹ yii.

Awọn tọọgi kan lo kọ lu Sunday Ọladunmoye to jẹ awakọ ọkan ninu awọn agbẹjọro to waa gbẹnu sọ fun oludije ẹgbẹ PDP ninu eto idibo naa, Amofin agba Eyitayọ Jẹgẹdẹ.

Ọpẹlọpẹ awọn ẹsọ alaabo ti wọn ranṣẹ pe ni wọn pana wahala naa, ti wọn si le awọn janduku oloṣelu ọhun kuro lagbegbe ile-ẹjọ.

Aarọ ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ni igbimọ ẹlẹni mẹta ti Onidaajọ Abubakar Umar ko sodi bẹrẹ ijokoo lori ẹjọ ti Eyitayọ Jẹgẹdẹ pe ta ko bi ajọ eleto idibo ṣe kede orukọ  Gomina Rotimi Akeredolu gẹgẹ bii ẹni to jawe olubori ninu eto idibo naa.

Ninu ọrọ akọsọ rẹ ki wọn too bẹrẹ igbẹjọ, Onidaajọ Umar ni ẹsun mẹta ọtọọtọ lo wa niwaju igbimọ ọhun ti wọn fẹẹ ṣiṣẹ le lori.

O bẹbẹ fun ifọwọsowọpọ awọn ti ọrọ kan, ki iṣẹ naa le rọrun fun wọn ni siṣe.

Leave a Reply