Arowolo rẹwọn ọdun mẹta he, foonu lo ji l’Ọrẹ

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Adajọ kootu Majisreeti to wa l’Odigbo, ti i ṣe ibujokoo ijọba ibilẹ Odigbo, ti ran ọkunrin ẹni ọdun mẹrindinlọgbọn kan, Arowolo Friday, lẹwọn ọdun mẹta, latari jijẹbi ẹsun ole jija ti wọn fi kan an.

Ni ibamu pẹlu ẹsun ti ọlọpaa agbefọba, James Usifo, ka si ọdaran ọhun lẹsẹ lasiko igbẹjọ, o ni ṣe ni Arowolo lọ si ile-itura kan to wa lagbegbe Akinjagunla, niluu Ọrẹ, lọjọ iṣẹlẹ naa, nibi to to ti ji foonu Abilekọ Joy Ọladokun, eyi ti owo rẹ to bii ẹgbẹrun mẹwaa Naira.

Bakan naa lo ni ọkunrin ọdaran ọhun tun huwa to le di alaafia ilu lọwọ pẹlu bo tun ṣe fi nọmba to wa lori foonu onifoonu to ji gba ipe ati atẹjisẹ, lai gba asẹ lọdọ obinrin to ni foonu naa.

Awọn ẹsun mẹtẹẹta to fi kan olujẹjọ ọhun lo ni o lodi labẹ abala irinwo din mẹwaa (390) ati ojilelugba le mẹsan-an ninu iwe ofin ipinlẹ Ondo ti ọdun 2006.

Olujẹjọ ọhun ko wulẹ fi asiko ile-ẹjọ naa ṣofo to fi gba pe oun jẹbi awọn ẹsun mẹtẹẹta ti wọn fi kan an, lẹyin eyi ni agbefọba dide, to si gba adajọ kootu ọhun nimọran lati bẹrẹ igbẹjọ lẹyẹ-o-ṣọka.

Nigba to n gbe idajọ rẹ kalẹ, Onidaajọ O. Ogunfuyi ni oun paṣẹ ki ọdaran ọhun lọọ fẹwọn ọdun mẹta jura lori ẹsun mẹtẹẹta tabi ko san ẹgbẹrun mẹẹẹdọgbọn Naira lori ẹsun kọọkan gẹgẹ bii owo itanran.

Leave a Reply