Arun ‘Koro’ ti dinku daadaa ni Naijiria o

Aderounmu Kazeem

Igbimọ to n ri si fifi-opin si itankalẹ arun koronafairọọsi ti kede wi pe, ajakalẹ arun buruku naa ti n kasẹ nilẹ daadaa ni Nigeria.

Alaga ajọ ọhun, Ọgbẹni Boss Mustapha, ẹni to tun jẹ akọwe agba fun ijọba apapọ lo sọ bẹẹ fawọn oniroyin lana-an Tọsidee, Ọjọbọ, niluu Abuja.

O ni, “Ti a ba wo oriṣiriiṣi igbesẹ ta a gbe pẹlu lilo imọ sayẹnsi, ati ṣiṣe awọn iwadii, paapaa ṣiṣe awokọṣe awọn orilẹ-ede mi-in loriṣiriiṣi, ilọsiwaju nla lo ba wa, o si han bayii pe idinku nla ti n ba itankalẹ arun buruku naa.”

O fi kun un wi pe oṣu kẹfa ree ti ijọba apapọ ti ṣe ifilọlẹ igbimọ ọhun, bẹẹ ni aṣeyọri nla to ṣe ko ṣai foju han. O ni o ṣe pataki ki awọn ọmọ Naijiria ranti pe eeyan to le ni ọgbọn miliọnu (30,026,460) ni arun buruku yii kọlu lagbaaye, nigba ti eeyan to fẹrẹ to miliọnu kan aabọ (1,380,223) si lugbadi aisan ọhun ni ilẹ Afrika nibi, ti eeyan to to ẹgbẹrun lọna ọgọta (56,6040) si fara gba a ni Naijiria wa.

Ṣa o, Boss Mutspaha ti waa kilọ fawọn eeyan orilẹ-ede yii lati tubọ maa ṣọra ṣe, paapaa bo ṣe jẹ pe ijọba apapọ ti ṣi papa ọkọ ofurufu atawọn ẹka ileeṣẹ mi-in pada. O ni ti awọn eeyan ko ba ṣọra daadaa, itakanlẹ arun ọhun tun le pada, eyi to le buru pupọ ju ti tẹlẹ lọ.

 

About Alaroye

Journalist, Press man and News Researcher of the federal Republic of Nigeria

Check Also

Nitori to ni oun yoo fopin si eto aabo ni Borno ati Yobe, PDP Ekiti sọrọ si Fayẹmi

Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti Ẹgbẹ PDPipinlẹ Ekiti ti yẹgẹ ẹnu si gomina ipinlẹ Ekiti, Dokita Kayọde …

Leave a Reply

//zikroarg.com/4/4998019
%d bloggers like this: