Faith Adebọla, Eko
Ọrọ ti wọn n pe lowe ti n ni aro ninu bayii lori ajakalẹ arun aṣekupani Koronafairọọsi nipinlẹ Eko, eeyan mẹsan-an larun naa ṣeku pa lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, nigba tawọn mẹrinlelaaadọfa ṣẹṣẹ lugbadi rẹ, ti wọn si dero ibudo itọju arun Koro.
Atẹjade ojoojumọ ti ajọ to n ri si idena arun nilẹ wa, NCDC, fi lede lafẹmọju ọjọ Iṣẹgun fihan pe lọjọ Mọnde ta a n sọrọ rẹ yii, aropọ eeyan ti kinni naa mu kaakiri orileede wa jẹ ọrinlelọọọdunrun ati meje (387), gẹgẹ bi ayẹwo iṣẹgun ti wọn ṣe ṣe fihan. Ẹgbẹrun kan ati ọgọrun-un meje lawọn ti wọn da silẹ lati maa lọ sile wọn, wọn layẹwo fihan pe ara wọn ti ya.
Pẹlu iṣiro yii, eeyan ti arun Korona ti pa nipinlẹ Eko ti di ọtalelẹẹẹdẹgbẹta ati mẹrin (664).
Ajọ NCDC ṣi n laago ikilọ pe arun Korona yii ko ṣee fọwọ dẹngbẹrẹ mu, wọn ni kawọn eeyan ma ṣe jawọ ninu titẹle awọn alakalẹ iṣọra ati idena arun naa.