Arun Koronafairọọsi tun ti pa eeyan mẹfa mi-in ni Kwara

Stephen Ajagbe, Ilorin

Lẹyin iku olori oṣiṣẹ gomina, Aminu Logun, eeyan mẹfa mi-in ni arun Korona tun ti pa nipinlẹ Kwara.

Atẹjade kan ti akọwe iroyin gomina, Rafiu Ajakaye, gbe sita lalẹ oni Ọjọru, Wẹsidee, ṣalaye pe ileewosan ẹkọṣẹ Fasiti Ilọrin, UITH, lawọn eeyan ọhun ku si.

O ni iye awọn to ti ku bayii ni Kwara jẹ mejila.

O ṣalaye pe awọn alaṣẹ ileewosan naa lo fi to ijọba leti pe ayẹwo tawọn ṣe fawọn to ku naa fi han pe Korona lo pa wọn.

Ajakaye ni lonii nikan, awọn mẹwaa lo tun ti ko arun naa, eyi si mu iye awọn to n gba itọju lọwọ jẹ ọgọrun-un kan le mẹrinlelọgbọn (134).

O waa ni ijọba ti pese ibudo ayẹwo mi-in, eyi ti yoo mu un rọrun fun araalu lati le ṣe ayẹwo ni kiakia, laipẹ yii ni wọn yoo si ṣi i.

About admin

Check Also

Nitori to ni oun yoo fopin si eto aabo ni Borno ati Yobe, PDP Ekiti sọrọ si Fayẹmi

Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti Ẹgbẹ PDPipinlẹ Ekiti ti yẹgẹ ẹnu si gomina ipinlẹ Ekiti, Dokita Kayọde …

Leave a Reply

//ashoupsu.com/4/4998019
%d bloggers like this: