ASUU Fasiti Ekiti n binu, wọn ni ijọba n din oṣiṣẹ ku, wọn si tun jẹ awọn lowo

Oluyinka Soyemi, Ado-Ekiti

Ẹgbẹ awọn olukọ fasiti (ASUU), ẹka Fasiti Ekiti (EKSU), ti sọ pe tijọba ba tiẹ da ẹgbẹ naa lapapọ lohun lori awọn nnkan ti wọn n beere fun, awọn ko ni i wọle ti wọn ko ba dahun sibeere tawọn.

Alaga ẹgbẹ naa ni Ekiti, Ọmọwe Kayọde Arogundade , ṣalaye pe ijọba ko da sọrọ fasiti naa, wọn ko ṣeto owo iranwọ, bẹẹ ni wọn n din awọn oṣiṣẹ ku. O ni awọn nnkan wọnyi ti da idiwọ nla silẹ lori eto ẹkọ, iwadii ijinlẹ ati idagbasoke ileewe ọhun lapapọ.

O kilọ pe ti iṣẹlẹ to n waye lọwọlọwọ yii ba tẹsiwaju, awọn ko ni i wọle tawọn olukọ fasiti to ku ba fagi le iyanṣẹlodi.

Arogundade sọ siwaju pe ileewe naa jẹ awọn ni aabọ owo-oṣu to ti to oṣu mẹẹẹdogun, iyẹn lẹyin ti wọn le awọn oṣiṣẹ to le ni ẹgbẹrun kan loṣu kejila, ọdun to kọja. O ni ijọba tun jẹ ileewe naa lowo iranwọ oṣu marun-un, bẹẹ ni inakunaa ko dinku lọdọ awọn alaṣẹ.

Bakan naa lo ni owo iranwọ ẹka imọ iṣegun tawọn ni ki wọn maa san lọtọ gẹgẹ bi awọn ileewe to ku ṣe n ṣe ko lojutuu, Ọjọgbọn Bamitalẹ Ọmọle to jẹ alakooso agba ileewe naa ati Gomina Kayọde Fayẹmi ko si mu gbogbo ileri ti wọn ṣe ṣẹ.

O waa ni awọn nilo afikun owo iranwọ, owo-oṣu tijọba apapọ jẹ ati aabọ aabọ owo-oṣu ti  ijọba ipinlẹ wọn jẹ tẹlẹ, bẹẹ ni ki wọn foju awọn to n da ileewe naa ru wina ofin.

Nigba to n fesi, Alukoro EKSU, Bọde Ọlọfinmuagun, ni gbogbo awọn ẹsun wọnyi lawọn yoo ṣagbeyẹwo nikọọkan, tawọn yoo si fesi ti asiko ba to.

Leave a Reply