Igbakeji aarẹ ilẹ wa tẹlẹ to tun n gbero lati dije dupo aarẹ lọdun to n bọ, Alaaji Atiku Abubakar, ti ṣabẹwo si ẹni to jẹ igbakeji fun nigba naa, Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ nile rẹ l’Abẹokuta ni ọjọ Abamẹta, Ṣatide, to kọja yii.
Ni nnkan bii aago mẹwaa kọja iṣẹju diẹ ni Oluṣẹgun Ọbasanjọ ki ọkunrin oloṣelu lati ipinlẹ Adamawa naa kaabọ si ile rẹ to wa ni Hilton Towers, niluu Abẹokuta.
Bo tilẹ jẹ pe ọkunrin naa ko ti i sọ ohun to gbe e lọ si ọdọ Ọbasanjọ, ohun tawọn eeyan n sọ ni pe ko si ohun meji ti ọkunrin naa tori ẹ lọọ ri baba naa ju erongba rẹ lati tun dije dupo aarẹ lọdun to n bọ lọ.
Ọdun 2007, 2011 ati 2019 lo ti kọkọ dupo aarẹ.