Ayọdele Fayọṣe, ọkan pataki ninu awọn aṣaaju ẹgbẹ oṣelu PDP sin Atiku Abubakar ni gbẹrẹ ipakọ, ṣugbọn ki Ọlọrun jẹ ki ọkunrin ara Adamawa naa gbọ ni. Fayoṣe ni arun jẹjẹrẹ, kansa buruku ni Peter Obi jẹ fun ẹgbẹ awọn, ati pe to ba ti jẹ awọn lara tan, afaimọ ki arun naa ma debi ẹgbẹ awọn yii lọjọ idibo. Ọrọ ti Fayoṣe n sọ ye e: Ibo ni Obi, aṣaaju PDP si loun naa tẹlẹ, ṣugbọn bo ti ṣe wa yii, ọpọ ọmọ Ibo yoo dibo fun un, ti Atiku ko si ni i ri kinni kan laduugbo wọn. Bakan naa ni Kwankwaso toun naa wa ni Kano, Fayoṣe ni ọkunrin naa yoo da wọn lagbo nu lapa ibẹ. Ọkunrin oloṣelu yii n ṣalaye ni, pe ti Atiku ba mọ iwọn ara rẹ, ko mọ bi yoo ti ṣe mu awọn gomina to n ba a ja yii mọra, ko si ṣe ohun ti wọn fẹ, bi bẹẹ kọ, omi le ti ẹyin wọ igbin lẹnu. Ṣugbọn ko jọ pe Atiku gbọ ọrọ naa, bo si gbọ, ko fẹẹ tẹle e. Bi ko ni ohun ti ajanaku jẹ tẹlẹ ikun, ko ni i ṣe ikun gbentọ si ọlọdẹ, ṣugbọn gbogbo ohun yoowu ti Alaaji Atiku Abubakar ba jẹ tẹlẹ ikun to fi n ṣe bo ti n ṣe yii ninu ẹgbẹ rẹ, afaimọ ki kinni naa ma pada di majele, to le ja a nifun ninu ibo to n bọ yii o. Sibẹ naa, ki i ṣe pe ọkunrin naa gbọ tabi o ṣetan lati yiwa pada, ohun to gbojule ni pe ibo awọn Fulani gbogbo yoo gbe oun wọle taara, ohun yoowu ti awọn eeyan kan ba ṣe tabi ti wọn ba sọ. Boya Atiku ko mọ, ọpọlọpọ eeyan lo n gbadura pe ko ni i wọle, nitori wọn nigbagbọ pe to ba wọle, iṣokan orile-ede Naijiria yoo daru, wahala yoo si pada ṣẹlẹ lẹyin ọla. Idi ti awọn eeyan fi n ro bayii si i ni pe ki i ṣe ohun to dara fun un lati jade pe oun yoo du ipo aarẹ Naijiria, lẹyin ti Buhari ba gbe kinni naa silẹ. Ohun to buru, to da awọn eto to ti wa nilẹ tẹlẹ ru ni. Eto to ti wa nilẹ ni pe nigbakigba ti ara Oke-Ọya ba ti ṣe olori Naijiria tan, awọn ara Isalẹ-Ọya ni wọn yoo pada tun ṣe e. Atiku ti wa ninu awọn ti wọn jọ n ṣe eeto yii bọ lati ọjọ yii wa, oun naa si ti fi ṣe kampeeni, o ti kilọ fawọn eeyan paapaa pe ki wọn ma ba awọn ara ilẹ Hausa du ipo nigba to ba jẹ akoko tiwọn ni. Ṣugbọn ni bayii, oun ti taku, o ni ko si ohun ti ẹnikẹni le sọ foun, oun yoo du ipo naa, o si ti lo gbogbo ọgbọn to ni lati ri i pe tikẹẹti ẹgbẹ oṣelu awọn, ọwọ oun lo ja bọ si, oun lo n du ipo aarẹ lorukọ PDP. Nigba to ti ṣe bo ti ṣe e yii, ko si ohun to ku ti iba ṣe ju lati fa oju awọn ẹya to ku ni Naijiria mọra, paapaa awọn ti wọn wa lati Isalẹ-Odo Ọya, awọn Ibo pẹlu Yoruba ati awọn Naija Delta. Ohun to si fi le ṣe bẹẹ ni ko ri i pe ipo pinpin ninu ẹgbẹ oṣelu naa lọ bo ti yẹ ko lọ. Atiku funra ẹ lo si le ṣe eyi. Nigba ti wọn yoo fi Iyorchia Ayuu ṣe alaga, nitori pe Oke-Ọya loun naa ti wa, ẹjẹ to jẹ ni pe to ba jẹ Atiku lo wọle, tabi ẹni yoowu lati adugbo awọn, oun yoo fi ipo alaga ẹgbẹ naa silẹ, ki ara Isalẹ-Oya waa gba ipo naa. Ṣugbọn nigba ti Atiku ti wọle tan, Ayu ta ku, o loun ko ni i fi ipo naa silẹ o. Ẹni kan ṣoṣo to le ba a sọrọ ko gbọ, Atiku ni, ṣugbọn o jọ pe ẹyin ẹ naa ni Atiku wa, Atiku gan-an lo jọ pe o n ti i ṣiṣe. Kin ni Atiku waa fẹ o, ṣe ki oun jẹ ondupo aarẹ fun PDP, ki gbogbo awọn oloye ẹgbẹ to ku naa si jẹ ara ilẹ Hausa ni. Ki lo de ti Ayu to ti ṣeleri tẹlẹ ko mu ileri naa ṣẹ. Odidi gomina marun-un n binu ninu ẹgbẹ oṣelu kan, sibẹ, Atiku n ṣe bii ẹni pe ko si ohun ti awọn gomina naa le ṣe, bẹẹ ọjọ lo n lọ yii. Bi awọn gomina maraarun yii ba binu jalẹ ti wọn ko ṣiṣẹ fun Atiku, bawo ni yoo ṣe ri ibo mu lati ipinlẹ wọn, ti ko ba si mu ibo ni ipinlẹ marun-un, ti Obi gba ilẹ Ibo mọ ọn lọwọ, ti wọn tun ba a pin ilẹ Hausa si wẹwẹẹ, nibo ni yoo gba wọle! Ṣugbọn boya o wọle ibo tabi ko wọle ibo gan-an kọ ni ọrọ to wa nibẹ, ohun to wa nibẹ ni iha ti o n kọ si iṣọkan Naijiria, ati ohun to ro nipa atunto ati atunṣe orile-ede wa. Ṣe loju tirẹ, ẹya miiran ko gbọdọ ba awọn Hausa-Fulani du kinni kan mọ ni, tabi ki awọn Hausa-Fulani maa wa nipo olori, ki awọn eya to ku maa sa tẹle wọn bii ẹru wọn ni. Ohun ti iwa ti Atiku hu ninu PDP jọ niyi to ba ṣe pe ko rẹni wi foun. Iwọ fẹẹ ṣe aarẹ, ki ara adugbo rẹ naa ṣe alaga ẹgbẹ, ki ẹ waa jọ maa pin ohun gbogbo bo ṣe wu yin, ki ẹ si kọyin sawọn ẹya to ku. Ṣugbọn iyẹn ko ni i ṣee ṣe, ohun ti oju alaigbọran si n ri, oju rẹ yoo ri i, oun naa yoo si mọ pe oun loun fọwọ ara oun ṣera oun.