Atunto nikan lo le yanju ọrọ ẹlẹyamẹya ni Naijiria-Akeredolu

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Gomina ipinlẹ Ondo, Rotimi Akeredolu, ti ni ṣiṣe atunto kiakia nikan lo le yanju ede-aiyede ati ọrọ ẹlẹyamẹya to n lọ lọwọ ni Naijiria.

Arakunrin ni o digba ti atunṣe ba de ba abala ojilelugba le mẹwaa (250) to wa ninu iwe ofin ọdun 1999 ki alaafia, ipindọgba ati idajọ ododo too le fẹsẹ mulẹ lorilẹ-ede Naijiria.

Akeredolu sọrọ yii ninu idanilẹkọọ kan to ṣe fawọn eeyan lasiko ayẹyẹ ikẹkọọ-gboye awọn akẹkọọ Fasiti Ọbafẹmi Awolọwọ to wa niluu Ile-Ifẹ, lọjọ Abamẹta, Satide, ọsẹ to kọja.

O ni o yẹ ki wọn gba ẹya kọọkan laaye ki wọn da duro, ki wọn le maa mojuto ọrọ eto ẹkọ, ilera, eto idajọ, ileeṣẹ ọlọpaa, ọgba ẹwọn atawọn nnkan alumọọni to ba wa nipinlẹ koowa wọn.

Aketi ni asiko ti to fun ijọba apapọ lati mu ẹru ara rẹ fuyẹ nipa fifun awọn ipinlẹ laaye ati maa mojuto eto ọrọ aje ati eto abẹle wọn funra wọn, ki ijọba apapọ kan maa mojuto gbogbo bi nnkan ba ṣe n lọ lawọn ipinlẹ.

Gomina ohun ni bi awọn ipinlẹ ṣe n woju ijọba apapọ ki wọn too ṣe ohunkohun fawọn araalu ti wọn n dari ko bojumu, bẹẹ ni ko si ni i ran idagbasoke Naijiria lọwọ.

O ni ofin fun awọn gomina lagbara lati maa ṣakoso gbogbo ilẹ to ba wa nipinlẹ wọn, ki wọn le lo o fun ọpọ nnkan amayedẹrun fawọn eeyan wọn ati pe aitẹle ofin yii lo ṣokunfa ọkan-o-jọkan akọlu tawọn ọdaran darandaran kan n ṣe sawọn agbẹ lori ilẹ wọn, ti wọn si tun n ba awọn ire-oko wọn jẹ.

Awọn ajoji kan ti ko sẹni to mọ wọn lo ni wọn n ya bo awọn ipinlẹ lọna aitọ, ti wọn si n ji awọn nnkan alumọọni to yẹ ki ilu fi sara rindin ta ni gbanjo.

Bakan naa lo tun gba ijọba apapọ nimọran lati faaye silẹ fawọn ẹya kọọkan ki wọn maa lo ede abinibi wọn, ki asọye ati agbọye baa le fẹsẹ mulẹ si i.

Nípa ti eto idibo aarẹ to n bọ lọdun 2023, Aketi ni ko dara rara ki ipo agbara maa fi si ọna kan, o ni idunnu oun ni ki wọn gba awọn eeyan ẹkun Guusu naa laaye lati di aarẹ nitori pe ibi ko ju ibi, ba a ṣe bi ẹru naa la bi ọmọ.

Leave a Reply