Florence Babaṣọla
Ọwọ ajọ to n gbogun ti iwa ibajẹ lorileede yii, Economic and Financial Crime Commission, ti tẹ ọmọkunrin kan, Austin Onyekachukwu, lori ẹsun pe o n pe ara rẹ ni ohun ti ko jẹ.
Laarin oṣu kẹjọ, ọdun 2018, si oṣu kẹfa, ọdun 2019, ni agbẹjọro fun ajọ EFCC, Suleiman Basheer, sọ fun kootu pe Austin huwa naa.
Gẹgẹ bi Basheer ṣe sọ nile-ẹjọ giga tijọba apapọ to wa niluu Oṣogbo lọjọ Aje, Mọnde, ọṣẹ yii, o ni olujẹjọ pe ara rẹ lobinrin fun awọn oyinbo, o si n lu wọn ni jibiti owo nla ko too di pe ọwọ tẹ ẹ niluu Oṣogbo, lẹyin ọpọlọpọ iwadii.
Nigba ti wọn beere boya Austin jẹbi ẹsun pipe ara ẹni lohun ti a ko jẹ ati jibiti lilu ti wọn fi kan an, o ni oun ko jẹbi.
Agbẹjọro rẹ, Ọlanrewaju Jayeọba, bẹ kootu lati faaye beeli silẹ fun un nitori pe akẹkọọ ṣi ni.
Onidaajọ Ayọọla Emmanuel fun Austin ni beeli pẹlu ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹta naira (#500,000) pẹlu oniduuro kan.
O ni baba to bi Austin gan-an lo gbọdọ ṣe oniduuro fun un, ko si mu ọmọ rẹ wa si kootu lọjọ kọkanla, oṣu kọkanla, ti wọn sun igbẹjọ si.