Awa la paayan meji nile Sunday Igboho – DSS

Ileeṣẹ ọtẹlẹmuyẹ ilẹ wa ti jade sita, wọn si ti jẹwọ pe loootọ loootọ, awọn lawọn ya wọ ile ajijagbara ọmọ Yoruba nni, Oloye Sunday Igboho, tawọn si paayan meji nibẹ lasiko ti awọn doju ibọn kọ ara awọn. Wọn ni ohun to fa ikọlu naa ni bi awọn ṣe gbọ pe awọn ohun ija oloro wa nile rẹ, ati pe o n lo o lati da wahala silẹ niluu.

L’Ọjọbọ, Tọsidee, ọse yii, ni wọn pe ipade oniroyin, nibi ti wọn ti sọ bayii pe ‘‘Laaarọ kutukutu Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kin –in-ni, oṣu keje yii, ni deede aago aago kan kọja iṣẹju mẹrinlelọgbọn ni a ya wọ ile Sunday Adeniyi ti gbogbo eeyan mọ si Sunday Igboho. Eyi ṣẹlẹ nitori awọn ọrọ aṣiri ta a gbọ pe ọkunrin naa nawọn ohun ija oloro nile. Ṣugbọn nigba ta a debẹ, niṣe ni awọn mẹsan-an ti wọn jẹ ọmọ ẹyin Igboho rẹ doju doju ibọn kọ wa. Mẹfa ninu wọn lo ko ibọn AK-47 dani, nigba ti awọn mẹta yooku gbe maṣinni gọọnu dani.

Lasiko ti a doju ija kọra wa ni meji ninu awọn ọmọọṣẹ rẹ ku, ti a si mu awọn to ku. Ibọn ba ọkan ninu awọn eeyan wa lọwọ, o si ti n gba itọju lọwọ.

Lẹyin eyi ni awọn ikọ wa wọ inu ile rẹ lati yẹ  e wo. Eyi lawọn ohun ti a ba nibẹ.

Ibọ AK-47 meje, Ibọn atamatase mẹta, AK-47 ọgbọ (30) ti ọta kun inu rẹ fọfọ, ọta ibọ bii ẹgbẹrun marun-un, ada marun-un, ọbẹ kan. Ibọn ilewọ meji apamọwọ  ti owo ilẹ okeere wa nibẹ kaadi ipọwo (ATM), kaadi, iwe irinna, iwe irinna ọkọ awọn oogun loriṣiiriṣii ati bẹẹ bẹẹ lọ.

 

Leave a Reply