Awọn ẹṣọ alaabo ti doola ẹmi ọlọpaa tawọn agbebọn ji gbe n’llọrin 

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Ileeṣẹ ọlọpaa ẹka tipinlẹ Kwara, pẹlu ifọwọsowọpọ ẹgbẹ fijilante ti doola ẹmi ọlọpaa kan, ASP Ahmed Yusuf, tawọn ajinigbe ji gbe lọjọ kọkanla, oṣu Kẹwaa, ọdun yii, lagbegbe Baba-Saka, Ọlọjẹ, Ilọrin.

Ninu atẹjade kan ti Alukoro ọlọpaa ni Kwara, Ọgbẹni Ọkasanmi Ajayi, fi sita lọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii, to tẹ ALAROYE lọwọ lo ti sọ pe ileeṣẹ ọlọpaa pẹlu ifọwọsowọpọ ẹgbẹ fijilante, ti doola ẹmi ọlọpaa ti awọn ajinigbe ji gbe nileegbe rẹ to wa ni agbegbe Ọlọjẹ, niluu Ilọrin. O tẹsiwaju pe inu igbo kan to paala laarin ipinlẹ Kwara ati Ọyọ, ni wọn ti ri ọlọpaa naa doola.

Ajayi ni Kọmisanna ọlọpaa, CP Paul Odama, lo pasẹ fawọn ẹṣọ alaabo lati ri i pe wọn doola ọlọpaa naa lai fara pa, ki wọn si ri i daju pe ọwọ ba awọn ajinigbe naa, ki wọn le fi wọn jofin.

O waa gboriyin fawọn ẹṣọ alaabo fun iṣẹ takuntakun ti wọn ṣe lati doola \gbofinro ọhun. ASP ti wa ni ileewosan bayii fun ayẹwo to peye, ti yoo si darapọ mọ mọlẹbi rẹ laipẹ.

Leave a Reply