Agbẹkọya ati ṣọja kọju ija sira wọn n’Ibadan, ni wọn ba yinbọn pa ọlọkada to n lọ jẹẹjẹ ẹ

Ọlawale Ajao, Ibadan

Ọlọkada lo fori ko iku ojiji nigba ti ẹgbẹ Agbẹkọya, iyẹn ọkan ninu awọn ẹgbẹ awọn ajijagbara Yoruba fija pẹẹta ni sẹkiteriati ijọba ipinlẹ Ọyọ, l’Agodi, n’Ibadan, ti i ṣe gbọngan ipade awọn ẹlẹgbẹjẹgbẹ ilẹ Yoruba kaakiri agbaye to waye laaarọ Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii.

Wahala bẹ silẹ nigba ti awọn ṣọja ko gba fun gbogbo awọn to waa ṣoju ẹgbẹ Agbẹkọya lati rọ wọ inu ọgba naa lẹẹkan naa, ṣugbọn ti awọn ọmọ ẹgbẹ ajijagbara yii sọ pe ta ni wọn lati maa fọwọ lalẹ le awọn lori ninu ilu awọn, wọn ni gbogbo awọn lawọn yoo jọ wọle papọ, nnkan kan ko si ni i tẹyin ẹ yọ.

ALAROYE gbọ pe nibi ti wọn ti n fa ọrọ yii mọra wọn lọwọ lọkan ninu awọn ọmọ ẹgbẹ Agbẹkọya ti binu ko ifọti fun ṣọja kan, nigba naa lawọn ṣọja jẹwọ ara wọn gẹgẹ bii jagunjagun pẹlu bi wọn ṣe ṣina ibọn bolẹ, ti ọrọ si di ẹni-ori-yọ-o-dile, paapaa fun awọn ti ko lóògùn arìndọ́ debi ti wọn yoo ba wọn jaáyán.

Adekunle Adeyẹmi tiṣẹlẹ ọhun ṣoju ẹ ṣalaye fakọroyin wa pe, “Ibọn ti awọn ṣọja n yin ko ba awọn Agbẹkọya lẹru, ọlọkada kan to n lọ jẹẹjẹ ẹ nibọn lọọ ba.

“Nibi ti wọn ti jọ n bara wọn fa a lọwọ lawọn ṣọja ti foonu awọn Operation Burst (ikọ eleto aabo ipinlẹ Ọyọ, eyi to ko awọn ṣọja, ọlọpaa atawọn oṣiṣẹ eleto aabo yooku papọ). Awọn yẹn ni wọn fi tiagaasi tu awọn Agbẹkọya ka ti alaafia fi pada jọba, to di pe gbogbo awọn to wa sibi ipade yẹn n wọle lọkọọkan ejeeji gẹgẹ bi awọn ṣọja to n ṣọ sẹkiteriati ṣe la a kalẹ.”

Ileewosan UCH la gbọ pe wọn sare gbe ọlọkada naa lọ, ko si ju wakati meji lọ lẹyin naa lakọroyin wa gbọ iroyin iku ẹ.

Nigba ti akọroyin wa pe SP Olugbenga Fadeyi ti i ṣe Alukoro fun ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ lati fidi iṣẹlẹ yii mulẹ, o loun ko mọ nipa iṣẹlẹ naa nitori ẹnikẹni ko ti i fi iroyin ọhun to awọn leti.

One thought on “Agbẹkọya ati ṣọja kọju ija sira wọn n’Ibadan, ni wọn ba yinbọn pa ọlọkada to n lọ jẹẹjẹ ẹ

Leave a Reply