Awọn agbebọn ji gbajugbaja oniṣowo epo l’Ekiti

Oluyinka Soyemi, Ado-Ekiti

Awọn agbebọn ti ji gbajugbaja oniṣowo epo kan, Alhaji Suleiman Akanji Akinbami, ni ọkan ninu awọn ileepo ẹ lalẹ ọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii.

Alhaji Akinbami la gbọ pe awọn agbebọn ọhun ji gbe nileepo ẹ to wa lọna ileewe Poli, niluu Ado-Ekiti.

ALAROYE gbọ pe ni nnkan bii aago mẹsan-an alẹ lawọn ajinigbe ọhun ya bo ibudo ọhun, ko si sẹni to le sun mọ ibẹ titi ti wọn fi gbe Alhaji lọ.

Alukoro ọlọpaa Ekiti,  ASP Sunday Abutu, fidi ẹ mulẹ pe ni nnkan bii aago mẹjọ aabọ niṣẹlẹ naa waye gẹgẹ bi iyawo ẹni ti wọn ji gbe, Abilekọ Mariam Akinbami, ṣe ṣalaye ni teṣan Odo-Ado, l’Ado-Ekiti.

O ni lẹsẹkẹsẹ ni ọga ọlọpaa teṣan naa ti lọ sibẹ, bẹẹ ni Kọmiṣanna, CP Tunde Mobayọ, ti ran ikọ ọlọpaa kan lati maa tọpinpin awọn ajinigbe ọhun.

 

O waa ni ileeṣẹ naa ti n ṣiṣẹ pẹlu ẹṣọ Amọtẹkun, fijilante atawọn ọdẹ lati gba Alhaji Akinbami pada laaye ati lalaafia.

Bakan naa lo ni kawọn araalu maa wo awọn ajoji ti wọn ba fura si, ki wọn si maa fi to awọn ọlọpaa leti ti wọn ba kẹẹfin iwa ọdaran kankan.

Leave a Reply