Ọlawale Ajao, Ibadan
Niṣe lawọn ọdaju eeyan pa ọkunrin oniṣowo kan, Ọgbẹni Maduabuchi Linus Onwuamanam nipakupa saduugbo Ọrẹmeji, ni Mọkọla, n’Ibadan.
Ile ọti, nibi ti baba ẹni ọdun mọkanlelaaadọta (51) yii ti n ṣe faaji lọwọ, laduugbo Ọrẹ-Meji, lagbegbe Mọkọla, lawọn gende mẹrin kan lọọ ka a mọ ni nnkan bii aago mẹsan-an alẹ ọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu karun-un, ọdun 2021 yii.
ALAROYE gbọ pe awọn ọdaran naa ko ba a rojọ kankan, bi wọn ṣe foju kan an ni ọkan ninu wọn yinbọn fun un, ṣugbọn ibọn ọhun ko ba a. Bo si ṣe ri i pe ẹmi oun lawọn ọdaju eeyan wọnyi fẹẹ gba loun naa ti sare dide nilẹ, to si gbiyanju lati sa asala fun ẹmi rẹ.
Ṣugbọn awọn ẹruuku ko fi i lọrun silẹ, wọn tun lọọ ka a mọbi to sa pamọ si, wọn si bẹrẹ si i ṣa a ladaa. Nigba ti wọn ri i daju pe o ti ku ni wọn too fi i lọrun silẹ, wọn si ta le awọn ọkada meji ti wọn gbe lọ ṣibẹ, wọn sa lọ raurau.
Ọgbẹni Onwuamanam, ẹni to ni ọpọlọpọ ile ati ṣoọbu kaakiri Ibadan yii ti ku ki awọn elẹyinju aanu ti wọn du ẹmi ẹ too gbe e deleewosan.
Nigba to n fidi iṣẹlẹ yii mulẹ, Agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ, DSP Adewale Ọṣifẹṣọ, sọ pe iyawo baba oniṣowo yii, Abilekọ Christiana, lo fiṣẹlẹ ọhun to awọn agbofinro leti ni teṣan wọn to wa laduugbo Mọkọla, n’Ibadan.
Awọn ọlọpaa ti bẹrẹ iwadii lori iṣẹlẹ naa gẹgẹ bi ọkunrin naa ṣe fidi ẹ mulẹ fakọroyin wa.