Awọn ṣọja dawọọ idunnu lori bijọba ṣe yọ Buratai, olori wọn tẹlẹ

Faith Adebọla

Fọnran fidio kan to gori atẹ ayelujara lafẹmọju Ọjọruu, Wẹsidee, ti ṣafihan bi awọn ọmọ ogun ṣe dana ariya, ti wọn dawọọ idunnu, ti wọn si fi ayọ wọn han latari bi ileeṣẹ Aarẹ ṣe kede iyọnipo awọn olori ileeṣẹ ologun mẹrin ati iyansipo awọn olori tuntun.

Ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, nijọba kede atunto yii.

Bawọn ṣọja naa ṣe n jo, ti wọn n yinbọn soke, ti wọn si n lu ilu, ni wọn n kọrin ayọ. Awọn ọmoogun ori ilẹ, ti Buratai ti jẹ olori wọn nigba kan lo pọ ju ninu fidio naa.

Leave a Reply