Awọn ṣọja yari, wọn lawọn o ni i yọju si igbimọ to fẹẹ gbẹjọ rogbodiyan to ṣẹlẹ ni Lẹkki 

Aderohunmu Kazeem

Igbimọ elẹni-meje ti ijọba Eko ṣagbekalẹ ẹ ti n kọwe ranṣẹ si awọn eeyan ti ọrọ kan lori rogbodiyan to ṣẹlẹ ni too-geeti Lẹkki logunjọ, oṣu kẹwaa, nigba ti awọn ṣọja kọlu awọn ọdọ to n ṣewọde, ti ọrọ ọhun si pada da wahala rẹpẹtẹ silẹ kaakiri Naijiria.

ALAROYE gbọ pe ileeṣẹ ologun ilẹ Naijiria ti sọ pe oun ko ni i da igbimọ kankan loun, afi ti ijọba Eko ba kọwe, to si fun oun laṣẹ lati yọju sibi igbimọ ọhun.

Agbẹnusọ fun ẹka ileeṣẹ ologun 81 Division, Ọgagun Ọṣọba Ọlaniyi, ti sọ pe ijọba Eko lo ran awọn lọ sibẹ, ijọba ọhun naa lo si gbe igbimọ ọhun kalẹ, to ba yẹ ki awọn ṣọja yọju si awọn igbimọ naa, o ṣe pataki ki ijọba kọ lẹta, awọn yoo si yọju lati jokoo pẹlu igbimọ ọhun.

Alaga igbimọ naa, Adajọ Doris Okuwobi, ti yoo bẹrẹ si i gbọ oriṣiiriṣii iṣẹlẹ to waye ni Lẹkki, to ba awọn oniroyin sọrọ sọ pe gbogbo awọn tọrọ kan pata lawọn ti kọwe ranṣẹ si pe wọn gbọdọ yọju. O ni ọrọ naa ko yọ ileeṣẹ ologun silẹ, tabi ileeṣẹ ọlọpaa atawọn mi-in laarin awujọ. Bakan naa lo sọ pe gbogbo iwa buruku ti awọn ẹṣọ agbofinro SARS paapaa hu si araalu lawọn yoo tu yẹwo yẹbẹyẹbẹ.

O fi kun un pe igbimọ naa ṣetan lati tu iṣu desalẹ ikoko lori ohun to fa wahala lọjọ naa, ati pe gbogbo awọn eeyan ti ọrọ ba kan pata lawọn yoo pe, ti wọn si gbọdọ yọju paapaa.

Ọgagun Ọlaniyi, iyẹn agbẹnusọ fawọn ṣọja sọ pe, “Araalu lawa naa, ki i ṣe pe a sadeede lọ sibẹ, wọn pe wa ni, igbimọ kankan ko si lẹtọọ lati maa fọrọ wa ileeṣẹ ologun lẹnu wo lori ohun to ṣẹlẹ ni Lẹkki. Awa naa ni ẹtọ daadaa labẹ ofin, ti wọn ba nilo wa, ijọba Eko ni yoo pe wa, ti a oo si yọju si wọn.

Ṣa o, igbimọ ẹlẹni-meje yii ti sọ pe ko tọna fun ileeṣẹ oloogun lati sọ pe awọn ko ni i yọju. Ọkan ninu awọn ọmọ igbimọ ọhun sọ pe o jẹ ohun to ku diẹ kaato ki adajọ kọwe si ileeṣẹ ologun, ki wọn si maa sọ pe awọn ko ni i yọju, bẹẹ agbara ti igbimọ yii ni fun un ni anfaani lati pe ẹnikẹni lati waa sọ tẹnu ẹ, paapaa awọn tọrọ ọhun kan.

 

Leave a Reply