Faith Adebọla
Awọn aṣofin Eko n wa ọkọ-ofurufu agbera-paa (hẹlikopita) mẹta. Ti ijọba ipinlẹ Eko ni wọn o, ṣugbon awọn aṣofin naa lawọn ko mọbiti wọn ha si. Nitori bẹẹ, wọn ti ke si kọmiṣanna feto ọrọ aje ati iṣuna, Ọgbẹni Samuel Egube, kọmiṣanna fun akanṣe iṣẹ (Special Duties), Ọgbẹni Tayọ Bamgboṣe-Martins, ati olori awọn oṣiṣẹ lọfiisi gomina, Ọgbẹni Tayọ Ayinde, lati yọju si wọn laisọsẹ.
Bakan naa lawọn aṣofin naa tun ke si awọn adari ajọ to n bojuto owo akanlo fun eto aabo nipinlẹ Eko, iyẹn Lagos State Security Trust Fund, LSSTF, lati yọju lori ọrọ ọhun, nitori awọn baalu yii kii ṣe olowo kekere, gbogbo ẹni ti ọro ba si kan ni wọn fẹ ko yọju si wọn.
Nibi apero wọn to waye lọjọ Aje ana ni Akojaanu ile aṣofin naa, Ọnarebu Mojisọla Miranda, ti dabaa pe ki wọn kọwe sawọn tọrọ kan lati waa wi tẹnu wọn lori ọrọ awọn hẹlikọpita to dawati ọhun, ati ki awọn aṣofin naa le mọ hulẹhulẹ adehun to wa laarin ijọba Eko ati ileeṣẹ Caverton Helicopters to n bawọn mojuto awọn baalu naa.
Gẹgẹ bo ṣe wi, ọdun 2007 lawọn aṣofin fontẹ lu u pe kijọba Eko da ajọ LSSTF silẹ lati ro eto aabo ipinlẹ Eko lagbara, ọdun 2015 si ni wọn ra awọn baalu agberapaa mẹta, labẹ akoso Akinwunmi Ambọde gẹgẹ bii gomina.
Olori ile igbimo aṣofin, Mudaṣiru Ọbasa, ni, “O maa wu mi pe ka pe awọn tọrọ kan lati waa sọ pato ibi ti awọn hẹlikọpita mẹtẹẹta wọlẹ si, boya wọn tiẹ ti n jẹra danu nibikan ni, tabi wọn ti n lo wọn fun nnkan mi-in, ka si tanna wo awọn iwe adehun to wa lori awọn dukia ijọba wọnyi.”
Ọnarebu Ọbasa ni oun ranti pe ilo ọna meji ni wọn pete awọn baluu naa fun, akọkọ ni ko ṣiṣẹ fun eto aabo, ẹẹkeji si ni ki wọn tun le fi pawo wọle. Tori ẹ, o dabaa pe ki ile beere eelo lawọn baluu naa ti pa wọle latọjọ yii, nitori owo ara Eko ni.