Awọn aṣofin Ọyọ da awọn alaga kansu ti wọn da duro pada

Ọlawale Ajao, Ibadan

Lẹyin ọsẹ kan ti wọn ti da awọn alaga kansu mẹtala kan duro, ileegbimọ aṣofin ipinlẹ Ọyọ ti da wọn pada sipo wọn.

Ninu ipade ti wọn ṣe nileegbimọ ipinlẹ ọhun l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii ni wọn ti kede igbesẹ naa.

Lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹta, oṣu kọkanla, ọdun 2020 yii, ni wọn fun awọn alaga ijọba ibilẹ naa niwee idaduro alainigbedeke.

Ẹṣẹ ti wọn tori ẹ jiya ọhun ni pe wọn kọ lati ṣalaye bi wọn ṣe lo awọn ohun eelo ti wọn fi n ṣiṣẹ oko ati iṣẹ idagbasoke ilu, eyi ti ijọba ipinlẹ Ọyọ ko fun wọn. Alaye yii lawọn aṣofin fẹ ki wọn waa ṣe fawọn laipẹ yii ti wọn fi kọwe ranṣẹ si wọn lẹẹmeji ọtọọtọ, ṣugbọn ti awọn eeyan naa ko fesi kankan.

Awọn alaga kansu afun-n-ṣọ tọrọ naa kan ni Ido, Oluyọle, Ila-Oorun Ariwa Ibadan, Iwọ-Oorun Ariwa Ibadan ati Ila-Oorun Ọyọ pẹlu awọn alaga ijọba ibilẹ Onidagbasoke bii Iwọ-Oorun Lagelu, Ṣoro, Ila-Oorun-Akinyẹle ati Aarin-Gbungbun Ogbọmọṣọ.

Lẹyin ikede idaduro awọn alaga wọnyi ni wọn ṣẹṣẹ fi akọsilẹ alaye ti wọn ti n beere lọwọ wọn lati ọjọ yii ranṣẹ sileegbimọ aṣofin. Nigba ti Ọnarebu Oluṣẹgun Popoọla ti i ṣe alaga igbimọ to n ri si ọrọ ijọba ibilẹ ati oye jijẹ nileegbimọ aṣofin ipinlẹ yii ka akọsilẹ awọn alaga naa si gbogbo ile leti ni wọn too dariji wọn, ti wọn si da wọn pada sipo wọn.

Nigba to n sọrọ lasiko ipade ọhun, Olori ile naa, Ọnarebu Debọ Ogundoyin, sọ pe ki awọn ko da awọn alaga kansu naa duro lati deede fiya jẹ wọn, bi ko ṣe lati ri i pe wọn lo awọn ohun eelo ijọba to wa lọwọ wọn daadaa, paapaa lati ri i pe wọn fi awọn katakata to wa lakata wọn ṣatunṣe awọn titi to nilo amojuto ijọba ni kiakia.

Leave a Reply