Awọn aṣofin PDP Ọṣun fẹsun kan abẹnugan ile, wọn lojuṣaaju rẹ ti pọ ju

Florence Babaṣọla

Mejilelogun lara awọn ọmọ ile-igbimọ aṣofin ipinlẹ Ọṣun ti ṣeleri atilẹyin wọn fun Olori ile, Ọnarebu Timothy Owoẹyẹ, wọn ni idari rẹ jẹ alakooyawọ.

Eleyii ko ṣẹyin ẹsun kan ti olori awọn ọmọ ile to kere ju, Kofoworọla Babajide, fi kan Owoẹyẹ laipẹ yii pe o n ṣe ojuṣaaju laarin awọn aṣofin ẹgbẹ PDP ati APC.

Kofoworọla sọ pe aba ti oun da lori bi ọna agbegbe ti oun n ṣoju ti ṣe di pampẹ iku ni abẹnugan ko kọbiara si, eleyii ti ko si ri bẹẹ fun awọn aṣofin ẹgbẹ APC.

O ni eleyii to buru ju ni bi olori awọn ọmọ ẹgbẹ to pọ ju nile-igbimọ aṣofin ṣe le oun pada nibi ipade idakọnkọ ti awọn oloye ile ṣe pẹlu Gomina Gboyega Oyetọla lọjọ to buwọ lu abadofin eto iṣuna ọdun 2021.

Ṣugbọn ninu ọrọ awọn aṣofin ẹgbẹ APC, wọn ni ko sigba kankan ti Ọnarebu Owoẹyẹ huwa to ta ko agbekalẹ ilana idari ile-igbimọ aṣofin, wọn ni awawi lasan ni Kofoworọla n wi.

Ninu atẹjade ti alaga ile to n ri si ọrọ iroyin ati ipolongo, Ọgbẹni Kunle Akande, gbe jade lo ti sọ pe bi ibaṣepọ to dan mọnran ṣe wa laarin ile-igbimọ aṣofin ati igbimọ alaṣẹ ipinlẹ Ọṣun lo n bi awọn ẹgbẹ alatako ninu.

Akande ṣalaye pe ko si igbesẹ kankan ti abẹnugan gbe to ṣẹyin gbogbo awọn ọmọ ile; yala latinu ẹgbẹ oṣelu APC tabi ti PDP, ko si bojumu rara fun awọn aṣofin ẹgbẹ PDP lati sọ pe abẹnugan ṣojuṣaaju.

O ni awọn yoo tẹ siwaju lati maa ba ijọba fọwọsowọpọ fun itẹsiwaju ati idagbasoke ipinlẹ Ọṣun lapapọ, nitori ijọba to lafojusun rere lai ka ti owo perete to n wọle fun un ni.

 

Leave a Reply