Ijọba apapọ ni kawọn akẹkọọ wọle lọjọ Aje to n bọ

Pẹlu bi ariyanjiyan ṣe n waye latijọ yii lori boya awọn akẹkọọ alakọọbẹrẹ ati girama yoo wọle lọjọ Aje to n bọ yii, ijọba apapọ orílẹ̀-ede Naijiria ti paṣẹ pe ki wọn pada sileewe ni Mọnde, ọjọ kejidinlogun, oṣu kin-in-ni, ọdun 2021 yii.
Igbese yii waye lẹyin ipade pẹlu awọn gomina, awọn kọmiṣanna eto ẹkọ, awọn olori ileewe atawọn alẹnulọrọ gbogbo lori bawọn akẹkọọ yoo ṣe pada sileewe. Ilu Abuja nipade ọhun ti waye lọjọ kẹrinla, oṣu kin-in-ni yii.

Oludari to tun jẹ agbẹnusọ nileeṣẹ eto ẹkọ l’Abuja, Ọgbẹni Ben Goong, ṣalaye ninu atẹjade to fi sita l’Ọjọbọ naa pe ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ to n bọ yii, ni gbogbo awọn fẹnuko si pe kawọn akẹkọọ wọle sileewe, kawọn obi atawọn alaṣẹ ileewe si tẹle gbogbo ofin to de Korona, lati dẹkun itankalẹ ẹ lawujọ awọn ọmọ.

Wọn fẹnu ko pe dandan ni kawọn akẹkọọ, olukọ atẹni gbogbo to n ṣiṣẹ layiika ileewe lo ibomu. Wọn ni dandan ni kawọn alaṣẹ ileewe pese nnkan ifọwọ sawọn aaye kan nileewe, ki wọn si ri i pe wọn n yẹ awọn ọmọ naa wo pẹlu irinṣẹ ti wọn fi n mọ bi ara ba ti gbona to ki wọn too wọle.

Yatọ si eyi, kilaasi ko gbọdọ kun akunfaya, bẹ́ẹ̀ ni awọn akẹkọọ ko gbọdọ sun mọ ara wọn ju, wọn ni wọn gbọdọ faaye silẹ fun itakete ni.

Ayẹwo yoo maa wa lati mọ bi wọn ṣe n tẹle awọn nńkan wọnyi si, Ọgbẹni Goong sọ pe kawọn ileewe tẹle e ni yoo ṣe wọn lanfaani.

Leave a Reply