Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Ibi gẹrẹjẹ la a ba’gba lo ku ti Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ n sọ fawọn to fẹ ko tun pada sẹgbẹ PDP lẹẹkan si i bayii. Ẹbọra Owu loun ko ṣoṣelu mọ, imọran lo ku toun yoo maa fun awọn to ba wa nibẹ.
Satide, ọjọ kejilelogun, oṣu kin-in-ni, ọdun 2022 yii, ni ọrọ yii tun jade lẹẹkan si i, nigba tawọn aṣaaju ẹgbẹ oṣelu PDP ti Ọbasanjọ jẹ ara wọn tẹlẹ, ṣabẹwo si i nile rẹ l’Abẹokuta.
Alaga ẹgbẹ PDP lapapọ, Iyorchia Ayu, awọn gomina atijọ mẹrin, awọn igbimọ amuṣẹṣe ninu PDP atawọn mi-in ni wọn lọọ ka Ọbasanjọ mọle, ti wọn fẹ ko tun pada si PDP, ko le baa fi atilẹyin rẹ fẹgbẹ naa bii ti tẹlẹ, ki wọn si le jawe olubori.
Awọn gomina atijọ to tẹle Ayu ni: Oluṣẹgun Mimiko, Sule Lamido, Donald Duke ati Liyel Imoke.
Ṣugbọn Oloye Ọbasanjọ sọ fun wọn pe, “Nnkan yoowu ki n ṣe laye mi, nitori mo di aarẹ lati ipasẹ PDP, PDP yoo maa wa laye mi lọ ni. Lati ọjọ ti mo ti fa kaadi PDP mi ya, lati ọjọ naa ni mi o ti i ki i ṣe ọmọ ẹgbẹ PDP mọ. Ọjọ naa ni mo si ti pinnu pe mi o ki i ṣe ọmọ ẹgbẹ oṣelu kankan mọ. Ibi gẹrẹjẹ ta a ba’gba naa ni ma a maa wa lọ”
Bakan naa lo sọ fun Alaga PDP, Ayu, pe ọrun rẹ ni iṣoro PDP ati ni Naijiria wa, o ni Ọlọrun yoo ba a gbe e.
Bo ti sọrọ naa tan ni Ayu naa sọ fun un pe to ba fi PDP silẹ, ẹjẹ PDP ko ni i fi i silẹ.
Ayu fi kun un pe ẹgbẹ awọn yoo maa nilo imọran Ọbasanjọ gẹgẹ bii baba ninu oṣelu Naijiria ni.
Ẹ oo ranti pe eekan ni baba yii ninu oṣelu Naijiria, ṣugbọn lọdun 2015,Ọbasanjọ fa kaadi to fi n jẹ ọmọ ẹgbẹ PDP ya, nitori ija kan to waye laarin oun ati Goodluck Jonathan.
Bo ti waa kuro lẹgbẹ naa to, awọn oloṣelu ki i yee wa a kiri fun imọran, iru rẹ lawọn PDP tun ba lọ s’Abẹokuta yii, ko too sọ fun wọn pe oun ko ṣe mọ.