Aderohunmu Kazeem
Alaga ajọ to n ri si pinpin awọn ohun eelo tijọba pese fun awọn araalu lasiko Korona nipinlẹ Ondo, Akin Olotu, ti ṣalaye pe ki i ṣe pe awọn ko ṣuga tawọn eeyan ba ninu ile ẹru ti wọn si ji ko lọ pamọ, o ni awọn fẹẹ ko o fun awọn ileeṣẹ to n ṣe burẹdi nipinlẹ Ondo ni, ki awọn le fi ba wọn dunaa-dura lati din owo burẹdi ku. O ni gbogbo ounjẹ lawọn pin pata, awọn aṣẹwo paapaa gba ninu ounjẹ korona yii.
O sọrọ yii lasiko ifọrọwerọ to ṣe pẹlu ileesẹ tẹlifiṣan Arise, ni Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii. Ọkunrin naa ṣalaye pe bii ṣuga ẹgbẹrun kan lawọn tọju pamọ sinu ile naa ki awọn janduku too ya lọ sibẹ lọọ ko o.
Olotu sọ pe gbogbo ounjẹ iranwọ ti wọn fun awọn lasiko korona lawọn pin kaakiri ijọba ibilẹ mejidinlogun to wa nipinlẹ Ondo. Awọn opo, awọn aṣẹwo, awọn arugbo atawọn alaboyun lo ni awọn pin awọn ounjẹ iranwọ naa kan.
O ni oun le fi gbogbo ẹnu sọ ọ pe ko si ounjẹ kankan ti awọn ṣẹku sibi kan, gbogbo ounjẹ to wa fun korona lawọn pin patapata. Bẹẹ ni fidio tawọn ya lasiko tawọn n pin in wa lati fi ṣe ẹri. O fi kun alaye rẹ pe ṣuga ti wọn ko wa fawọn nipinlẹ Ondo ti pọ ju lawọn fi tọju eyi ti awọn janduku lọọ ji ko ọhun. Ati pe ṣuga nikan lo wa ninu ile ẹru naa, ko si ounjẹ mi-in nibẹ.
O ni awọn to wọle ko ṣuga tawọn tọju naa ti kuro ni awọn ti ebi n pa, bi ko ṣe awọn ọdaran ati janduku.