Awọn aṣọbode ti mu Yusuff, egboogi oloro lo gbe wọlu

Adewale Adeoye

‘Bi wọn ba lawọn ko ni i yee gbe egboogi oloro wọlu wa, awa paapaa ko ni i yee fọwọ ofin mu wọn, gbogbo ọgbọn ti wọn le da pata la mọ, bi wọn ba yọ nibuu, awa paapaa maa yọ looro ni. Gbogbo awọn tọwọ tẹ ati ohun ta a gba lọwọ wọn la ti ko fawọn ajọ to n gbogun ti gbigbe egboogi oloro nilẹ wa, National Drug Law Enforcement Agency’ (NDLEA), ki wọn le ba wọn ṣejọ. Ko saaye rara fun iwa ibajẹ lorileede yii mọ’. Eyi lọrọ to n jade lẹnu ọkan lara awọn ọga agba aṣọbode ilẹ wa, ‘ Nigerian Custom Service’, Dọkita Ben Oramalugo, ẹka ti ipinlẹ Kebbi, lasiko to n sọ nipa aṣeyọri wọn fawọn aṣoju ajọ NDLEA ti wọn waa gba awọn oogun oloro ti wọn gba lọwọ awọn ọdaran tọwọ tẹ.

ALAROYE gbọ pe ọwọ Yusuff Suleman, to jẹ ọkan lara awọn oniṣowo egboogi oloro ninu ilu naa ni wọn ti gba ẹru ofin yii, lọjọ kọkanla, oṣu Kẹfa, ọdun 2023, lakooko to fẹẹ ko o wọnu ilu naa.

Ben ni awọn kan ni wọn ta awọn lolobo nipa iṣẹ laabi ti Yusuff n ṣe laarin ilu, tawọn si tete lọọ dena de e lojuna marosẹ kan ti wọn n pe ni Kamba Kyanagakwai, nibi to maa gba gbe ọja ọhun kọja wọnu inu ilu wa, tọwọ si tẹ ẹ.

Lara awọn ẹru ofin ti wọn ba lọwọ Yusuff ni obitibiti apo igbo, egboogi oloro kan ti wọn n pe ni Diazepam, wọn ni ibi palapala inu mọto ni Yusuff tọju egboogi oloro Diazepam ọhun si.

Oga awọn aṣọbode yii ni gbara tawọn ti fọwọ ofin mu un lo ti jẹwọ pe loootọ loun n ṣowo egboogi oloro niluu naa.

Ni ipari ọrọ rẹ, o ni ko saaye fun awọn oniṣẹẹbi ti wọn fẹẹ maa gbe egboogi oloro wọlu wa lati apa ipinlẹ Kebbi, nitori wọn yoo foju wina ofin tọwọ ba tẹ wọn.

 

Leave a Reply