Dada Ajikanje
Awọn ọmọ ile-igbimọ aṣofin mẹsan-an ni wọn ti ta ko bi wọn ṣe yọ igbakeji olori ile-igbimọ aṣofin ipinlẹ Ondo, Ọgbẹni Irọju Ogundeji.
Ninu lẹta kan ti wọn kọ si olori ile-igbimọ aṣofin ọhun, Ọgbẹni Bamidele Oloyeloogun, eyi ti gbogbo wọn fọwọ si pata ni wọn ti sọ pe igbesẹ ti wọn fi yọ igbakeji olori ile-igbimọ aṣofin ọhun ko bofin mu rara.
Wọn ni igbesẹ wọn ọhun ta ko ofin orilẹ-ede Naijiria tọdun 1999, bẹẹ ni ko ba ilana eto iṣakoso ile-igbimọ aṣofin ọhun mu paapaa.
Ninu awọn ọmọ ile-igbimọ aṣofin bii ogun to fọwọ si bi wọn ṣe yọ ọ, mẹsan-an ninu wọn ti sọ pe awọn ko lọwọ nibẹ rara.
Ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ni wọn gbe igbesẹ ọhun, ninu eyi ti wọn ti sọ pe ọmọ ile igbimọ aṣofin ogun ninu mẹrindinọgbọn ti wọn wa nile aṣofin Ondo lo yọ ọkunrin naa danu lori ẹsun oriṣiriiṣi aṣemaṣe.
Loju ẹsẹ naa ni wọn ti fi ẹlomi-in rọpo ẹ, iyẹn Ọgbẹni Samuel Aderọboye, ẹni to ti ṣe igbakeji nile-igbimọ aṣofin ọhun ri.
Awọn aṣofin mẹsan-an yii naa ni wọn ti kọkọ ta ko igbesẹ tawọn ẹlẹgbẹ wọn gbe lasiko ti wọn fẹẹ yọ igbakeji gomina ipinlẹ Ondo, Agboọla Ajayi, nipo.