Nibo lẹyin n gbe, nibo lẹyin wa: Nigba ti ẹgbẹ Dẹmọ kọwe pe ki wọn ma ti i fi Awolọwọ silẹ lọgba ẹwọn

Nigba ti awọn eeyan bẹrẹ si i pariwo lẹyin ti wọn ti dibo ọdun 1964 tan pe ki wọn fi Oloye Ọbafẹmi Awolọwọ to wa lẹwọn silẹ ko maa lọ sile ni alaafia, inu awọn kan n dun, ṣugbọn dajudaju, inu ẹgbẹ Dẹmọ, bẹrẹ lati ọdọ olori ẹgbẹ naa ti i ṣe Oloye Ladoke Akintọla ati awọn aṣaaju ẹgbẹ wọn gbogbo ko dun rara si ọrọ yii, n lawọn naa ba fi ibinu gbe iwe kan jade. Eyi ni iwe naa ti Ẹgbẹ Dẹmọ kọ jade sinu iwe iroyin Daily Times lọjọ kẹtala, oṣu keji, ọdun 1965:

Ki ẹ too maa sọ pe ki wọn fi Awolọwọ silẹ lẹwọn, ẹ jẹ ka ranti awọn nnkan wọnyi o:

‘’Ninu oṣu kejila, ọdun to kọja yii, ati nitori ibo ti a di nigba naa, wahala ba orilẹ-ede wa debii pe awọn eeyan ro pe nnkan yoo daru fun wa ni. Ṣugbọn ọgbọn ati ọna ti a gba yanju ọrọ naa laarin ara wa, ti a si tun pada di ọkan naa jẹ ohun to ya gbogbo aye lẹnu. Bi a waa ṣe bọ ninu eyi, o yẹ ka maa ṣọra daadaa o, nitori oju ni alakan fi n ṣọri, ki ohun to ṣẹlẹ naa ma tun ṣẹlẹ si wa mọ. Awọn kan ti bẹrẹ ariwo bayii, ariwo wọn ti wọn si n pa ni pe wọn fẹ ki ijọba apapọ yọ Oloye Ọbafẹmi Awolọwọ, ẹni ti ile-ẹjọ giga Eko kan sọ sẹwọn ọdun mẹwaa lodun 1963, lori ẹsun idaluru ati ifipagbajọba, jade ni ọgba ẹwọn to wa, ko waa maa lọ sile ẹ ni alaafia.

Itara lasan lawọn kan fi n sọrọ yii o. Awọn mi-in n sọ ọ lasan nitori ifẹ ti wọn ni awọn ni si Awolọwọ, awọn mi-in si ni ki wọn yọ ọ lẹwọn nitori ohun to ṣe nigba ti Naijiria fẹẹ gbominira. Iyẹn ni pe bi Naijiria ba fẹẹ parẹ ko parẹ loju awọn yii ni, nitori ti ara wọn lasan. Eeyan o tiẹ gbọdọ gbagbe awọn kan ti wọn wa, to jẹ wọn mọ pe bi Awolọwọ ba jade lẹwọn, ijẹ tun bẹrẹ fawọn nidii oṣelu niyẹn, imọ-tara-ẹni-nikan yii lawọn si fi n ṣe ohun ti wọn n ṣe, ti wọn n pariwo pe afi ki Awolọwọ jade lẹwọn, ẹni to ba si n gbọ ohun wọn, yoo ro pe wọn fẹran Awolọwọ denudenu ni, wọn ko ni i mọ pe tara wọn ni wọn n ṣe. Bi awọn mi-in ṣe n gbe ọrọ yii kalẹ ninu wọn pẹlu etekete ko le jẹ ki eeyan ma fura pe ẹtan ni gbogbo kinni yii, wọn kan n fi ariwo yii tan awọn eeyan naa ni.

Ṣe ẹ ri i, bo ba jẹ nitori pe eeyan kan fẹran ẹni keji ni wọn yoo fi maa yọ eeyan jade lẹwọn ni, ko ni i si ọdaran kan ninu ọgba ẹwọn wa nibikibi lorilẹ-ede yii, abi bawo lẹni kan ṣe maa wa ti ko ni i si ẹni kan to kuku fẹran ẹ rara, koda ki tọhun jẹ eeyan buruku aye toun tọrun. Ni iru ọrọ to ba ṣe pataki si orilẹ-ede bayii, ẹ jẹ ka ba ara wa sọ ootọ ọrọ, ki i ṣe ifẹ tabi itara leeyan yoo fi ṣe e, tabi ariwo lasan ti awọn kan n pa kiri. Ọrọ pe ki wọn fi olori ẹgbẹ Action Group silẹ lọgba ẹwọn ki i ṣe ọrọ ariwo tabi itara, ọrọ to jẹ mọ eto aabo ni, iyẹn leeyan si ṣe gbọdọ wo o finnifinni. Ki i ṣe awọn ẹgbẹ awo kan ni wọn sọ Awolọwọ sẹwọn, ile-ẹjọ ti wọn gbe dide lati wadii iwa ọdaran to hu lo da a lẹbi lẹyin iwadii ati ẹri gidi, ohun to sọ ọ dero ẹwọn niyẹn. Ṣebi oun ati awọn ẹlẹgbẹ ẹ kan ni wọn jọ mu, awọn mi-in ko ṣaa tori ẹ dero ẹwọn ninu wọn.

Ṣugbọn lẹyin iwadii ni wọn da Awolọwọ lẹbi. O fẹẹ dalu ru, o fẹẹ fipa gbajọba, ṣebi ohun ti ile-ẹjo to ga ju lọ nilẹ yii ṣe ni ko maa lọ sẹwọn niyẹn. Ki eeyan loun fẹẹ fipa gbajọba! Ẹṣẹ nla buruku gbaa ni! Boya o ri ijọba naa gba tabi ko ri i gba, aburu to maa n ti iru idi ete bẹẹ jade ki i dara, yoo si ta ba araale, yoo ta ba ara oko, ọpọ awọn ibi ti wọn ti fipa gbajọba bẹẹ ni orilẹ-ede wọn ki i toro fungba pipẹ. Bo ba jẹ pe a ko ni awọn ọlọpaa to mọ iṣẹ wọn bii iṣẹ, ti ki i ṣe pe wọn ri Awolọwọ ati awọn eeyan ẹ ti wọn jọ fẹẹ gbajọba yii, ta lo mọ ohun ti iba ṣẹlẹ si orilẹ-ede wa. Ibi yoowu ti wọn ba ti gbiyanju lati fipa gbajọba ki i pada bọ sipo fungba pipẹ. Awolọwọ fẹẹ fibọn gbajọba ni, ẹṣẹ to lodi si ofin Ọlọrun ati tawa eeyan, sibẹ, awọn abọbaku ati ọlọpọlọọ-yi-sodi to wa ninu ẹgbẹ wọn ko mọ pe o yẹ ki ọga awọn jiya ẹṣẹ ẹ, ẹni to fẹẹ fipa gbajọba!

Ọna ti awọn ọrẹ Awolọwọ ati awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu ẹ n tọ yii, ọna to kun fun ẹgun ati afọku igo ni, wọn yoo kan fara pa lasan ni. Gbogbo eeyan ni ẹlẹṣẹ, Olọrun ko si fẹ iku ẹlẹṣẹ bi ko ṣe ko ronupiwada. Bi Awolọwọ ba fẹẹ jade lẹwọn ko too di pe asiko ti wọn da fun un pe, ko si ohun meji to le fa iyẹn ju aanu ijọba lọ. Eleyii ki i ṣe nnkan tuntun labẹ ofin wa, ijọba lagbara lati ṣe aanu fun ẹlẹwọn ti wọn ba fẹẹ ṣe aanu fun. Ṣugbọn yoo ti han ninu iwa ati iṣe iru ẹlẹwọn bayii pe o ti ronupiwada daadaa, ti wọn si ti mọ pe ko ni i ṣe iru nnkan wọnyi to ṣe tẹlẹ mọ. Awolọwọ dalu ru, o si fẹẹ fipa gbajọba, o fẹẹ ba eto aabo ati iṣọkan ilẹ wa jẹ. Se bi wọn ba tun fi i silẹ, ṣe ko tun ni i bẹrẹ gbe igba ohun to ṣe ku tẹlẹ, ṣe ko tun ni i fi oṣelu ẹ yọ ijọba ati araalu lẹnu mọ.

Ṣugbọn awọn ọmọlẹyin Awolọwọ ko fẹẹ gbọ eyi ti a sọ yii o, ohun kan naa ti awọn n tẹnu mọ ni pe Awọlọwọ sẹ bẹbẹ ki Naijiria too gbominira. Ṣe oun nikan lo ṣiṣẹ ominira ọhun ni! Ẹ jẹ ki a ṣe alaye ọrọ yii pẹlu afiwe kan: Obinrin kan loyun, o si ni wahala pupọ ko too ri ọmọ bi. Awọn olugbẹbi pupọ ni wọn ṣiṣẹ lori ẹ to fi ri ọmọ naa bi. Ọmọ yii waa dagba tan, o si ti n ṣe daadaa. Lọjọ kan, ija de laarin oun ati ọkan ninu awọn to gbẹbi ẹ, n ni agbẹbi yii ba pa a. Wọn waa mu olugbẹbi naa, wọn ju u sẹwọn nitori iwa to hu, awọn kan wa n sọ pe ki wọn fi i silẹ lọgba ẹwọn, nitori pe ọkan ninu awọn to gbẹbi ọmọ naa ni. Iru ọrọ radarada wo niyẹn. Ọrọ ti awọn ọmọlẹyin Awolọwọ n sọ niyẹn. Ki wọn too le fun Awolọwọ ni idariji lọgba ẹwọn, o gbọdọ tuuba, ka si ri apẹẹrẹ pe ko ni i dalu ru mọ, awa ko ti i ri iru ẹ bayii o.

Awọn ọmọlẹyin Awolọwọ ti wọn sọ pe ki wọn fi i silẹ yii, iwa idaluru ni wọn ṣi n ṣe kiri o, ti wọn n ko awọn wuligansi kiri lati fi pa awọn ọmọ Ẹgbẹ Dẹmọ lara. Bẹẹ ọmọlẹyin Awolọwọ tabi ọrẹ ẹ ni wọn n pe ara wọn. Gbogbo ẹni to ba ti waa sọ pe ki wọn ma ṣe bẹẹ mọ, koda titi dori awọn ọba ati awọn ijoye, wọn yoo ni ẹru Ẹgbẹ Dẹmọ ni, wọn yoo tun maa ba tọhun ja. Awọn ọrẹ ojiji ti Awolọwọ ni yii gan-an lo n ko ba a, wọn ko tun ọrọ rẹ ṣe rara. Bi ẹ ti n wo awa ninu Ẹgbẹ Dẹmọ yii, omi aanu wa loju wa, alaaanu si ni wa, ko si ohun to ṣẹlẹ ti a ko le ba Awolọwọ bẹbẹ ki wọn dari ji i pẹlu iwa buruku to hu si orilẹ-ede yii, Ṣugbọn ki awa too ṣe bẹẹ, afi ka ri i pe oun naa ti tuuba, o si ṣeleri lati ma huwa kan ti yoo dalu ru bo ba jade, paapaa ju lọ, awọn ọmọlẹyin ẹ gbọdọ so ewe agbejẹ mọwọ, ka ri iwa ọmọluabi lara wọn. Ki Ọlọrun yọ Awolọwọ lọwọ awọn ọrẹ ẹ tuntun o.’’

Bayii ni Ẹgbẹ Dẹmọ wi ninu iwe ti wọn kọ jade, Nathaniel Kotoyẹ ti i ṣe akọwe ẹgbẹ naa lo si gbe iwe naa jade lorukọ wọn. Ọrọ inu iwe naa ka awọn eeyan laya, ohun ti wọn si fọkan si ni pe ko si bi wọn yoo ti ṣe fi Awolọwọ silẹ lọgba ẹwọn titi ti wọn yoo fi di ibo Western Region tan lọdun 1965, eleyii si jẹ ohun to ka awọn eeyan laya, wọn ni awọn yoo da kinni naa ru gbẹyin ni.

Leave a Reply