Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Awọn aṣofin ipinlẹ Ọṣun ti fun alakooso akanṣe iṣẹ omi ilu Ileṣa, Ẹnijinnia Tawa Williams, ni gbedeke wakati mẹrinlelogun lati sọ pe owo ẹsun riba to fi kan awọn aṣofin naa ko ri bẹẹ.
Ẹnjinnia Tawa lo sọ lori redio kan l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii, pe igbimọ awọn aṣofin to n ri si ọrọ omi ati nnkan alumọọni ibẹ beere ẹgunjẹ miiọnu marun-un dọla lọwọ oun lori iṣẹ akanṣe naa.
O ni gbogbo awọn aṣofin loun kọkọ ro pe wọn fiwe pe oun, afigba ti oun atawọn alabaaṣiṣẹpọ oun debẹ lọjọ naa ti awọn si ba awọn igbimọ ọhun.
Ẹnijinnia yii fi kun ọrọ rẹ pe bi oun ṣe sọ pe oun ko ni ẹgunjẹ kankan lati fun wọn ni wọn halẹ mọ oun pe awọn yoo sọ fun awọn oniroyin pe ayederu ni gbogbo irinṣẹ tawọn lo fun ipese omi naa.
A oo ranti pe nibẹrẹ ọsẹ yii ni Gomina Ademọla Adeleke kede idaduro Ẹnijinnia Tawa lori ẹsun pe gbogbo owo tijọba apapọ ati Banki Islam ya ijọba ipinlẹ Ọṣun fun akanṣe iṣẹ naa ni ko yọ rara.
Gomina ṣalaye pe ko si iṣẹ kankan teeyan le tọka si pe wọn ṣe nibẹ pẹlu owo bantubantu ti wọn gba ọhun, nitori naa, ki iṣẹ iwadii bẹrẹ lori iṣẹ ti wọn ṣe nibẹ, ki Ẹnjinnia Tawa si da mọto ayọkẹlẹ onimiliọnu lọna aadọrin Naira to jẹ tijọba to n gun pada.
Ṣugbọn ọrọ ti Williams sọ yii bi awọn aṣofin ninu, nibi ijokoo wọn lọjọ Tọsidee ni wọn ti fun obinrin naa ni wakati mẹrinlelogun lati ko ọrọ rẹ jẹ.
Abẹnugan ile, Timothy Owoẹyẹ, nipasẹ Akọwe iroyin rẹ, Kunle Alabi, ṣalaye pe, ṣe lobinrin naa fẹẹ fi ọrọ yii ba awọn aṣofin lorukọ jẹ. O ni ajegbodo rẹ n wa ẹni kunra ni.
Gẹgẹ bi Owoẹyẹ ṣe sọ, apapọ owo ti wọn fẹẹ na lori eyi ti Tawa n sọrọ rẹ yii jẹ miliọnu meji dọla, bawo waa lo ṣe mu ọpọlọ dani pe awọn aṣofin n beere ẹgunjẹ miliọnu marun-un dọla lọwọ ẹ.
O ni ti obinrin naa ko ba yi ọrọ rẹ pada, awọn yoo wọ ọ lọ si kootu lati lọọ ṣalaye ohun to ri lọbẹ to fi waro ọwọ, nitori awọn ko le gba ki ẹnikẹni fi orukọ rere awọn yi ẹrẹ rara.