Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Ile-igbimọ aṣofin ipinlẹ Ondo ti yọ Ọnọrebu Irọju Ogundeji gẹgẹ bii igbakeji abẹnugan.
Irọju to n ṣoju awọn eeyan ijọba ibilẹ Odigbo kin-in-ni ni wọn yọ laaarọ ọjọ Isẹgun, Tusidee, lori ẹsun hihu iwa to le ko ẹrẹ ati idọti ba ile-igbimọ ọhun.
Awọn aṣofin bii ogun ni wọn kọwọ bọ iwe iyọnipo rẹ ninu awọn ọmọ ile mẹrindinlọgbọn, loju ẹsẹ ni wọn si ti yan Ọnarebu Samuel Aderọboye to n ṣoju awọn eeyan ijọba ibilẹ Odigbo keji rọpo rẹ.
Lẹyin ti wọn yọ Irọju tan ni Olori ile, Ọnarebu Bamidele Ọlẹyẹlogun, tun kede ṣiṣe atunto si awọn ipo kan nile-igbimọ aṣofin ọhun.
Ninu atunto tuntun naa ni wọn ti yọ ọmọ ẹgbẹ oṣelu Zenith Labour Party to n ṣoju awọn eeyan ijọba ibilẹ Iwọ-Oorun Ondo kin-in-ni, Ọnọrebu Tọmide Akinribido, kuro nipo olori ọmọ ile to kere ju lọ, ti wọn si fi Festus Akingbasọ lati Ijọba ibilẹ Idanre rọpo rẹ.
Taofik Ọladele, aṣoju awọn eeyan ijọba ibilẹ Ariwa Iwọ-Oorun Akoko keji, ni wọn kede orukọ rẹ bii akojaanu ile, oun lo gba ipo lọwọ Adeyẹmi Ọlayẹmi to jẹ aṣoju awọn eeyan ijọba ibilẹ Ọwọ keji.
Ọnarebu Emmanuel Ogunmọlasuyi to wa lati ijọba ijọba ibilẹ Ọwọ kin-in-ni ni wọn yan gẹgẹ bii olori awọn ọmọ ile to pọ ju lọ.
Ipo yii ti ṣofo lati bii osu mẹrin sẹyin, lẹyin ti Ọnarebu Jamiu Suleiman Maito kọwe fipo naa silẹ ni kete ti Agboọla Ajayi kede erongba rẹ lati dupo gomina.