Awọn aṣofin Ọ̀yọ́ gba ijọba nimoran lati gbe ọja Ṣáṣá lọ sibomi-in

Ọlawale Ajao, Ibadan

 

Ileegbimọ aṣofin ipinlẹ Ọyọ ti dabaa pe kí ìjọba ipinlẹ naa gbe ọja Ṣáṣá, n’Ibadan, kuro nibi to wa yii, lọ sibo mi-in to jinna sigboro.

Wọn ni èròngbà awọn pẹlu àbá naa ni lati dènà laasigbo to ṣee ṣe ko tun máa wáyé ninu ọja ọhun lọjọ iwaju.

Te o ba gbagbe, l’Ọjọbọ, Tọ́sìdeè, to kọja, ni rogbodiyan bẹ silẹ laarin Yoruba atawọn Hausa agbegbe naa, ninu eyi ti ọpọ eeyan ati dukia ti ṣegbe, titi dori ọ̀kẹ́ àìmọye ṣọọbu ati dukia inu ọja Ṣáṣá.

Aṣofin tó n ṣoju ẹkun idibo Akínyẹlé Keji nileegbimọ aṣofin ipinlẹ Ọyọ, Ọnarebu Ọlatunde Kẹhinde, lo gbe aba naa lọ siwaju ile l’Ọjọbọ, Tosidee.

Igbimọ awọn aṣofin naa gbà pe ibi ti ọja nla ọhun wa ko gbà èrò to n ṣe kárà-kátà níbẹ̀ mọ pẹlu ọja rẹpẹtẹ ti wọn n ko wọ ibẹ lojoojumọ.

Wọn waa gba ijọba niyanju lati ṣí ọja Ṣáṣá nídìí lọ sí ààyè tuntun tí yóò tobi dáadáa ju ibi to wa lọwọlọwọ bayii lọ.

Nigba to n fi aidunnu ẹ̀ hàn sí iṣẹlẹ to mu kí ìjọba ti ọja nla ọhun pa, olori ileegbimọ aṣòfin ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Ọnarebu Debọ Ogundoyin, sọ pe nitori pe awọn Hausa atawọn Yoruba to wa ni Ṣáṣá ko fi pẹlẹpẹlẹ yanju iṣẹlẹ to da laasigbo naa silẹ lo jẹ ko ba nnkan jẹ tó bẹẹ.

O ni bi ijọba ba le gbe gbe ọja Ṣasa lọ sí ààyè nla tuntun, Iru ija to le là ọpọ ẹmi ati dukia lọ bẹẹ ko ni í wáyé mọ

Leave a Reply