Faith Adebọla, Eko
Nibi ijokoo wọn to gbẹyin lọdun yii, lawọn aṣofin Eko ti bura fun aṣofin ti wọn ṣẹṣẹ dibo yan, Ọnarebu Saheed Wasiu Ọbafẹmi, gẹgẹ bii aṣoju agbegbe Koṣọfẹ keji, nipinlẹ Eko.
Ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii, ni wọn bura fun un, ti wọn si gba a wọle sileegbimọ ọhun.
Tẹ o ba gbagbe, Saheed Ọbafẹmi to dije lorukọ ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, (APC), l’Ekoo, ni ajọ eleto idibo kede pe o jawe olubori ninu atundi ibo to waye lọjọ karun-un, oṣu yii, lati rọpo Oloogbe Ọnarebu Tunde Buraimọh to jade laye ninu oṣu keje, ọdun yii, latari bo ṣe lugbadi arun Korona nigba naa.
Nigba to n ki Ọnarebu Saheed kaabọ, abẹnugan ile gba aṣofin naa niyanju lati di alafo ti Tunde Buraimọh ṣi silẹ, ko si fọwọsọwọpọ pẹlu awọn ọnarebu to ku fun igbega ipinlẹ Eko.
Yatọ si awọn mọlẹbi ati ọrẹ to pesẹ sibi eto ọhun, Sẹnetọ Tokunbọ Abiru toun naa ṣẹṣẹ wọle sipo aṣofin agba l’Abuja naa wa nikalẹ.