Awọn aafaa yii to tọọnu lori iyawo oniyawo, wọn ni oro to gbọdọ ṣe ko too dọmọ ẹgbẹ awọn ni

Awọn aafaa mẹta yii, Tukur Danazumi; ẹni ọdun mọkandinlogun, Abubakar Yahuza; ẹni ogun ọdun, ati Rufai Sanusi; ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn, ṣi wa latimọle ọlọpaa ni Katsina bayii, nitori iyawo oniyawo to fẹẹ darapọ mọ ẹgbẹ wọn ti wọn lawọn mẹtẹẹta ba lo pọ, to si ṣe bẹẹ loyun, to tun bimọ obinrin kan tẹnikan ko ti i mọ baba rẹ bayii.

  Niṣe lawọn ọlọpaa ṣafihan awọn aafaa mẹta yii lolu ileeṣẹ wọn nipinlẹ Katsina, lẹyin ti ọkọ obinrin ti wọn fun loyun ti fẹjọ wọn sun tawọn ọlọpaa si ti ko wọn.

Ẹgbẹ kan ti wọn n pe ni ‘Hakika’ lawọn ọkunrin mẹta yii n ṣe, ẹgbẹ ẹlẹsin Islam ni wọn pe e, ṣugbọn awọn to sun mọ wọn sọ pe wọn ko yatọ si Boko Haram, nitori iṣe wọn gbogbo ko ba ẹsin Islam mu.

Beeyan ba fẹẹ wọ ẹgbẹ ọhun, wọn ni to ba ti jẹ obinrin ni, awọn mẹtẹẹta yii ti wọn jẹ olori ẹgbẹ yoo ba a sun, nitori lara eto igbaniwọle niyẹn.

Ọmọbinrin ti wọn ni wọn ba sun to di ẹjọ yii, Zainab Ahmed, lo n jẹ. O ti lọkọ ni Katsina, orukọ ọkọ naa ni Abdullahi Isiyaku.

Nnkan ko rọgbọ lẹyin igbeyawo ni ọkọ iyawo fi gba ilu Eko lọ, to lọọ ṣiṣẹ aje, to si fi iyawo rẹ silẹ sọdọ awọn obi iyawo naa, pe ki wọn maa ba oun mojuto o.

  Ọdun 2020 to kọja yii lọkọ tirafu, ko too de niyawo rẹ ti lọọ darapọ mọ ẹgbẹ Hakika, wọn lawọn yoo ba a sun ko too di ara awọn o, iyawo naa si ni iyẹn ki i ṣe wahala, ki wọn waa ṣe ohun ti wọn fẹẹ ṣe koun le di ara wọn.

Zainab funra ẹ jẹwọ eyi fawọn ọlọpaa lẹyin ti wọn mu awọn aafaa adamọdi naa tan, o ni wọn sọ foun pe awọn yoo ba oun sun, oun si gba, nitori ẹgbẹ naa wu oun. Abajade ibalopọ naa ni oyun to ni to si fi bimọ obinrin, ọmọ ọhun ti pe oṣu mẹrin bayii.

Nigba ti Abdullahi ti i ṣe ọkọ rẹ pada de loṣu to kọja yii to ba ọmọ lọwọ iyawo rẹ, to si mọ pe iyawo oun ko loyun nigba toun kuro nile, ẹnu ya a, inu bi i. Lẹyin gbogbo ẹ niyawo ṣalaye nipa awọn Hakika fun un, ọkunrin naa ko si lọọ ba wọn ja, kaka bẹẹ, teṣan ọlọpaa ẹka Danja, laduugbo wọn, lo mu ẹjọ lọ. Ṣugbọn o loun mọ pe iyawo oun kọ lo gbe ara ẹ lọọ ba awọn ẹgbẹ naa, wọn lo nnkan fun ni ko fi le kọ ohun wọn.

Nigba  tọlọpaa gbe awọn aafaa naa, wọn lawọn ko ba Zainab sun, ko sohun tawọn ko le fi bura si i. Ọkan ninu wọn tilẹ ni ki wọn ko gbogbo awọn lọ sọsibitu pẹlu Zainab atọmọ ẹ, ki wọn lọọ ṣayẹwo DNA ti wọn fi n mọ ẹni to ni ọmọ fawọn.

O lo da oun loju pe ọmọ naa ko ni i jẹ tẹnikẹni ninu awọn mẹtẹẹta. Ṣugbọn Zainab ni awọn mẹtẹẹta ni wọn ba oun sun, wọn si ṣe e karakara to fi dọmọ ni.

Bi bẹẹ ni tabi bẹẹ kọ, gbogbo ẹ dọwọ ijọba. Ṣugbọn awọn eeyan ko sọ daadaa nigba ẹgbẹ Hakika yii. Wọn ni wọn lodi sopo marun-un ẹsin Islam, wọn ki i kirun, wọn ki i gbaawẹ Ramadan bo ṣe jẹ dandan to, wọn si ni wọn fẹran ṣìná ṣiṣe de gongo. Wọn ni wọn maa n ba ara wọn laya sun ṣere ni, atiyawo oniyawo pẹlu.

Leave a Reply