Awọn adigunjale pa ọlọpaa kan lasiko ti wọn kọ lu ileefowopamọ ni Ọtun-Ekiti

Taofeek SurdiqAdo-Ekiti 

Ọlọpaa kan ti wọn ko ti i darukọ rẹ lo gba ọrun lọ lojiji ninu akọlu kan tawọn janduku ṣe si banki igbalode kan  ni Ọtun-Ekiti, nijọba ibilẹ Mọba, nipinlẹ Ekiti. Ipo Inspẹkitọ ni wọn lọlọpaa yii wa, oun si ni ẹṣọ alaabo to wa lẹnu iṣẹ lasiko tawọn adigunjale yii ya bo banki naa.

Akọlu ti wọn ṣe si banki si yii l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii, ni yoo jẹ igba keji laarin ọdun kan ti iru akọlu bẹẹ yoo waye nileefowopamọ naa, eeyan mẹrin ni wọn fẹmi wọn ṣofo ninu akọlu ti iṣaaju.

Ọkunrin kan to jẹ olugbe ilu naa, Ṣọla Atọlagbe, sọ nipa iṣẹlẹ yii fun wa pe awọn afurasi ọdaran wọlu ọhun ni deede aago marun-un aabọ irọlẹ, ti wọn si bẹrẹ si i yinbọn soke lati le awọn eeyan ati awọn onibaara banki naa danu.

Ṣọla ni ado oloro kan ni wọn fọ mọ ilẹkun igbalode to wọnu banki naa, bi ado oloro naa ṣe bu gbamu ni ilẹkun naa fa ya, wọn wọnu ile, wọn si ko ọpọ owo ti ẹnikẹni ko ti i mọ iye rẹ wọ inu ọkọ bọọsi alawọ funfun ti wọn gbe wa.

Nigba to n sọrọ lori iṣẹlẹ naa, Alukoro awọn ọlọpaa ni ipinlẹ Ekiti, Ọgbẹni Sunday Abutu, fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, o ṣalaye pe  loootọ ni awọn adigunjale naa fẹẹ fi ado oloro wọle sinu banki naa, ṣugbọn wọn ko raaye wọle.

O ni iwadii ṣi n lọ lọwọ.

Leave a Reply