Awọn adigunjale yinbọn pa ọlọdẹ meji nileepo kan l’Akurẹ

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Awọn ọlọdẹ meji ti wọn gba lati maa sọ ileepo nla kan to wa lagbegbe Custom, loju ọna marosẹ Ondo, niluu Akurẹ, lawọn adigunjale kan yinbọn pa loru ọjọ Abamẹta, Satide, ọsẹ to kọja, mọju ọjọ Aiku, Sannde ọsẹ yii.

ALAROYE fidi rẹ mulẹ lati ẹnu Ọgbẹni Buhari Ashiru to jẹ ọkan ninu awọn alaboojuto ileepo ọhun pe awọn oṣiṣẹ kan to fẹẹ wọṣẹ ni nnkan bii aago marun-un aabọ idaji ọjọ Aiku, Sannde, ni wọn ri oku awọn ọlọdẹ mejeeji ninu agbara ẹjẹ, nibi ti wọn pa wọn si.

O ni awọn adigunjale naa gbiyanju lati ja ibi agbara ileepo ọhun, ti wọn ko ri i ṣe titi ti wọn fi sa lọ.

Ọkan ninu awọn ti wọn pa ọhun, Isreal, lo ni o ti to bii ọmọ ọdun marundinlaaadọta nigba ti ẹni keji rẹ ko ti i ju ẹni ọdun mejidinlọgbọn pere lọ.

Oku awọn mejeeji ṣi wa ni mọṣuari ileewosan ijọba to wa l’Akurẹ lasiko ta a fi n kọ iroyin yii lọwọ.

Leave a Reply