Awọn adigunjale yinbọn pa eeyan meji lasiko ti wọn kọ lu banki l’Aramọkọ-Ekiti  

Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti

Niṣe lawọn eeyan ilu Aramọko-Ekiti n sa kijokijo nirọlẹ ọjọ Aje, Mọnde, nigba ti awọn adigunjale kọ lu ileefowopamọ kan to wa niluu naa.

Ọlọpaa kan ati ẹṣọ oju popo kan lo gba ọrun lọ lojiji ninu iṣẹlẹ naa ti awọn adigunjale naa fi yinbọn fun bii ọgbọn iṣẹju.

Gẹgẹ bi awọn ti iṣẹlẹ naa ṣoju wọn ṣe sọ, wọn ni awọn adigunjale naa ti wọn ko din ni meje ni wọn gba oju ọna kan to wa lati Igede-Ekiti ni nnkan bii agogo mẹfa irọlẹ, ti wọn si fi ado oloro ja ilẹkun ile ifowopamọ naa, ki wọn too wọ gbagede ile banki ọhun.

Iṣẹlẹ yii lo jẹ igba keji ti awọn adigunjale yoo ya wọn banki naa.

A gbọ pe ki awọn adigunjale naa too de ibi ti ile ifowopamọ yii wa ni wọn ti kọkọ kọ lu awọn ọlọpaa to wa ni ẹnu ibode ilu naa, ti wọn si pa ọlọpaa kan. Bakan naa ni ẹṣọ ojupopo kan to n lọ pẹlu ọkọ ayọkẹlẹ rẹ naa sadeede ja si aarin wọn ti wọn si yinbọn lu u.

Wọn ṣalaye pe ado oloro ti wọn fi ja ilẹkun ẹnu ọna ile ifowopamọ naa ati ibọn ti awọn adigunjale naa yin lagbara pupọ, to si ba awọn eeyan ilu naa l’ẹru.

 

A gbọ pe awọn adigunjale naa gbe owo ti ẹnikẹni ko ti i mọ iye rẹ lọ.  Lẹyin ti wọn ṣiṣẹ buruku yii tan ni wọn gba opopona tijọba ipinlẹ Ekiti ṣẹṣẹ ṣe to lọ lati ilu naa si Erinjiyan ati Ikọgọsi Ekiti.

Nigba to n sọrọ lori iṣẹlẹ naa, Alukoro ọlọpaa nipinlẹ Ekiti, Ọgbẹni Sunday Abutu, sọ pe eeyan meji lo ku lasiko iṣẹlẹ naa.

O ṣalaye pe awọn ọlọpaa duro kanpe lasiko akọlu naa, ti wọn si ri ọkọ meji gba lọwọ awọn adigunjale ọhun.

O ṣalaye pe ọlọpaa kan ti wọn pa lasiko idigunjale naa wa layiika ileefowopamọ ọhun  ni wọn fi yinbọn pa a. Bakan naa ni ẹṣọ oju popo ti wọn pa naa n bọ pẹlu ọkọ ayọkẹlẹ rẹ, ti awọn adigunjale naa si yinbọn lu u.

O ṣeleri pe ọwọ ọlọpaa yoo tẹ awọn adigunjale naa.

Leave a Reply