Awọn afẹmiṣofo ti wọ ilẹ Yoruba, wọn ti wa nipinlẹ Ọṣun ati Ogun-Gani Adams

Monisọla Saka

Aarẹ Ọna Kakanfo ilẹ Yoruba, Iba Gani Adams, ti sọ pe  ohun ti ọrọ eto aabo to dẹnukọlẹ yii n tọka si ni ami pe Naijiria ti fẹẹ da wo lulẹ.

Ninu ọrọ to sọ latẹnu Akọwe iroyin rẹ, Kẹhinde Aderẹmi, Adams gbara ta lori inira ti wọn n ko ba awọn eeyan, pẹlu aiṣedeede awọn olori wa, toun ti bi awọn ti wọn wa nipo aṣẹ ṣe n lẹdi apo pọ mọ awọn ọdaran apanijaye yii.

O rọ Aarẹ Muhammadu Buhari lati yee kawọ bọtan, o fi kun un pe gbogbo kudiẹ kudiẹ to n ṣẹlẹ lasiko yii tumọ si pe eto aabo ilẹ yii o ṣẹnuure.

“Dọla kan ni wọn ti n ṣẹ si ẹẹdẹgbẹrin Naira (700) yii. Ijọba to ba dọla ni owo ti ko to igba Naira nigba to dori ipo lọdun 2015 ree o.

‘‘Ọrọ ti waa di ki awọn mọlẹbi maa pe jọ da ọgọrun-un miliọnu Naira fawọn ajinigbe.

“Bẹẹ, owo ti wọn n da fawọn ọdaran yii, ohun ija oloro mi-in ni wọn yoo fi ra, awọn ijọba si fọwọ lẹran, wọn n wo”.

Oloye ilẹ Yoruba yii sọ pe lẹyin ti wọn ba jiiyan gbe, ti wọn si tun paayan tan, Aarẹ wa o ni i ri nnkan mi-in ṣe ju pe ko pe olori awọn oṣiṣẹ, ko fi atẹjade lede, lo ba tan.

Adams ni ọrọ naa ti doju ẹ debii pe awọn agbesunmọmi funra wọn n dunkooko lati ji Aarẹ, awọn gomina atawọn aṣofin gbe “.

O sọrọ pẹlu itara pe, aimọye lẹta lawọn ajọ DSS kọ si ijọba lori eto aabo, ko too waa di pe wọn ṣakọlu si ọgba ẹwọn Kuje.

O ni Nigeria n wọlẹ lọ, afi bii ẹni pe a ko nijọba lorilẹ-ede yii mọ.

Nigba to n tẹsiwaju, o ni,”O da bii pe Abuja gan-an ti kun ilu tawọn afẹmiṣofo n yọ lẹnu, ki wọn yaa tọwọ ọmọ wọn bọṣọ, ki wọn ma gbero pe awọn fẹẹ wọ apa iha guusu Ila Oorun, nilẹ Yoruba wa.

“A o ni i gba wọn laaye ki wọn ba ilẹ wa jẹ. A n rọ awọn gomina lati ṣe ipade pajawiri lori eto aabo pẹlu awọn eekan atawọn tọrọ kan”.

“Nitori a mọ gbogbo erongba wọn lati waa ṣakọlu s’Ekoo, Ibadan, nipinlẹ Ọyọ, Abẹokuta nipinlẹ Ogun. Ki awọn gomina wa lapa Iha Guusu Ila Oorun jọwọ ji giri, ki wọn waa kun awọn ọmọ ogun wa lawọn ijọba ibilẹ ipinlẹ kọọkan tori awọn araabi ti ni ibuba lawọn inu igbo ipinlẹ Ọṣun ati Ogun.

 

Leave a Reply