Faith Adebọla
Ọjọ buruku ni ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹrindinlogun, oṣu Kẹta yii, jẹ fun ileeṣẹ ọlọpaa ilẹ wa, meje lara awọn agbofinro to n ṣiṣẹ aabo ilu nipinlẹ Niger, lawọn janduku afẹmiṣofo mu balẹ.
Ba a ṣe gbọ, nnkan bii aago mẹsan-an owurọ lawọn agbebọn naa yọ lojiji sawọn ọlọpaa naa nibi ti wọn ti n ṣọ oju popo nilu Ngaski, ni kansu Ngaski, nipinlẹ ọhun, wọn ṣina ibọn fun wọn, wọn si pa ọlọpaa mẹrin.
Wọn lawọn agbebọn naa ti kọkọ kọwe ṣaaju sawọn araalu naa pe awọn maa ṣakọlu si wọn laipẹ, eyi si ti mu ki ọpọ eeyan filu silẹ, bo tilẹ jẹ pe wọn o mọ ọjọ pato ti wọn fẹẹ wa.
Awọn agbebọn naa tun ya bo ileeṣẹ kan ti wọn ti n ṣe tomato, GB Foods Africa, ileeṣẹ nla ni, ṣugbọn ki wọn too debẹ, awọn oyinbo Chinese ti wọn n ṣiṣẹ nibẹ ti gbọna ẹyin sa lọ.
Wọn lawọn agbebọn naa tun ya bo ẹka ileeṣe ọlọpaa ilu Nasko, wọn yinbọn pa ọga ọlọpaa (DPO) teṣan naa, CSP Umar Mohammed Dakin atawọn ọlọpaa meji.
Ni ipinlẹ Kebbi, bakan naa, eeyan meje lawọn eeṣin-o-kọku yii mu balẹ, awọn ẹṣọ alaabo fijilante lo pọ ju ninu wọn.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa Niger ti fidi iṣẹlẹ yii mulẹ ninu atẹjade kan to fi lede lalẹ ọjọ Tusidee.
Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ ọhun ṣalaye ninu atẹjade naa pe nnkan bii ẹẹdẹgbẹta (500) lawọn agbẹbọn naa, o ni niṣe ni wọn ya bo teṣan ọlọpaa Nasko, nibi ti DPO ti n ṣeto boun atawọn ọmọlẹyin rẹ ṣe maa koju wọn lọwọ ni wọn de, ti wọn si yinbọn fun nigbaaya.