Ọlawale Ajao, Ibadan
Nibi ipade ti awọn eeyan yii, pẹlu apapọ igbimọ Olubadan ṣe ni Gbọngan Mapo, n’Ibadan, lọsan- Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ karun-un, oṣu kin-in-ni ọdun 2022 yii, ni wọn ti kede ọrọ naa fun gbogbo aye gbọ.
Lara awọn to wa nibi ipade ọhun ni Ọba Lekan Balogun funra rẹ, to jẹ Ọtun Olubadan ilẹ Ibadan lọwọlọwọ; Balogun ilẹ Ibadan, Ọba Owolabi Akinloye; Aṣipa Olubadan, Ọba Eddy Oyewọle; Ọtun Balogun, Ọba Tajudeen Ajibọla ati Ọba Lateef Gbadamọsi ti i ṣe Osi Balogun ilẹ Ibadan.
Awọn agba ijoye Ibadan yooku, ti wọn tun jẹ igbimọ afọbajẹ ilu naa ni Ọba Abiọdun Kọla Daisi (Ẹkẹrin Olubadan), Ọba Amidu Ajibade (Ẹkarun-un Olubadan), Ọba Adebayọ Akande (Abẹsẹ Olubadan) ati Ọba Kọla Adegbọla ti i ṣe Aṣipa Balogun ilẹ Ibadan.
Tẹ o ba gbagbe, gbogbo awọn agba ijoye Ibadan, yatọ si Osi Olubadan, iyẹn Agba-Oye Rashidi Ladọja, ẹni ti ko ba wọn kopa ninu ipade yii, nijọba nipinlẹ Ọyọ, labẹ gomina ana, Sẹnetọ Abiọla Ajimọbi, fi jọba lori agbegbe koowa wọn lọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu kẹjọ, ọdun 2017.
Ṣaaju lọmọ oye tuntun naa, Ọba Lekan Balogun ti ki idile Olubadan to faye silẹ, Ọba Saliu Akanmu Adetunji, ilu Ibadan, ati Gomina ipinlẹ Ọyọ, Ẹnjinnia Ṣeyi Makinde, ku ara fẹra ku Olubadan ana, eyi to lọọ dara pọ mọ awọn baba nla ẹ lọjọ Aiku, Sannde, ọjọ keji, oṣu kin-in-ni, ọdun 2022 yii.
Ni kete ti Ọba Adetunji ti waja lọrọ kan ti bẹrẹ si i ja ran-in-ran-in kiri pe ẹni ti ipo ọba ilu nla yii kan ko dape mọ, wọn ni baba ti rọ lapa rọ lẹsẹ, bẹẹ lo tun fọ loju.
Lati ta ko ahesọ ọrọ naa, ikuuku mejeeji lỌba Balogun kọkọ ju bii igba ti abẹṣẹẹ-ku-bii-ojo ba pinnu lati fi ikuuku da batani si alatako rẹ lara. O ṣeyi lati fi han gbogbo aye pe oun ko nipenija ara ati pe perepere leegun ara oun pe.
O waa rọ gbogbo ọmọ Ibadan lati kọti ikun si gbogbo ahesọ iroyin to le da omi alaafia ilu ru, eyi ti wọn le ti maa gbọ lẹnu ọjọ mẹta yii.
Nipa eto bi wọn yoo ṣe fẹlomi-in jọba lẹyin ipapoda Ọba Adetunji, Ọba Balogun sọ pe “igbimọ awọn afọbajẹ ti n gbe igbesẹ to yẹ pẹlu gomina ipinlẹ yii lati ri i pe ẹni tipo Olubadan tọ si gori itẹ ni ibamu pẹlu aṣa taa fi n jọba nilẹ yii”.
Lẹyin naa l’Ọtun Balogun ilẹ Ibadan, Ọba Tajudeen Ajibọla ati Ọba Amidu Ajibade ti i ṣe Ẹkarun-un Olubadan fopin si awuyewuye to n lọ nigboro pe o ṣee ṣe ki ẹjọ to wa ni kootu mu ipalara ba eto lati fi Olubadan tuntun jẹ.
Gẹgẹ bi Ọba Ajibọla ati Ọba Ajibade ṣe ṣalaye, “ẹjọ to wa ni kootu ko ni nnkan kan an ṣe pẹlu ọrọ ẹni to yẹ ko jẹ Olubadan tuntun. Gbogbo wa la ti mọ pe Ọba Lekan Balogun nipo Olubadan kan, ta a ṣi ti fọwọ si i. Ilana ta a fi n jOlubadan ti wa nilẹ, ko si si nnkan kan to maa da a ru”.